I. Kro 4:1-4
I. Kro 4:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
AWỌN ọmọ Juda; Faresi, Hesroni, ati Karmi, ati Huri, ati Ṣobali. Reaiah ọmọ Ṣobali si bi Jahati; Jahati si bi Ahumai, ati Lahadi. Wọnyi ni idile awọn ara Sora. Awọn wọnyi li o ti ọdọ baba Etamu wá; Jesreeli ati Jisma, ati Jidbaṣi: orukọ arabinrin wọn si ni Selelponi: Ati Penueli ni baba Gedori, ati Eseri baba Huṣa. Wọnyi ni awọn ọmọ Huri, akọbi Efrata, baba Betlehemu.
I. Kro 4:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn ọmọ Juda ni: Peresi, Hesironi, Kami, Huri, ati Ṣobali. Ṣobali ni ó bí Reaaya. Reaaya sì bí Jahati. Jahati ni baba Ahumai ati Lahadi. Àwọn ni ìdílé àwọn tí ń gbé Sora. Àwọn ọmọ Etamu ni: Jesireeli, Iṣima, ati Idibaṣi. Orúkọ arabinrin wọn ni Haseleliponi. Penueli ni baba Gedori. Eseri bí Huṣa. Àwọn ni ọmọ Huri, àkọ́bí Efurata, tí ó jẹ́ baba Bẹtilẹhẹmu.
I. Kro 4:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn ọmọ Juda: Peresi, Hesroni, Karmi, Huri àti Ṣobali. Reaiah ọmọ Ṣobali ni baba Jahati, àti Jahati baba Ahumai àti Lahadi. Àwọn wọ̀nyí ni ẹ̀yà ará Sorati. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Etamu: Jesreeli, Iṣima, Idbaṣi, orúkọ arábìnrin wọn sì ni Haseleponi Penueli sì ni baba Gedori, àti Eseri baba Huṣa. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Huri, àkọ́bí Efrata àti baba Bẹtilẹhẹmu.