KRONIKA KINNI 4:1-4

KRONIKA KINNI 4:1-4 YCE

Àwọn ọmọ Juda ni: Peresi, Hesironi, Kami, Huri, ati Ṣobali. Ṣobali ni ó bí Reaaya. Reaaya sì bí Jahati. Jahati ni baba Ahumai ati Lahadi. Àwọn ni ìdílé àwọn tí ń gbé Sora. Àwọn ọmọ Etamu ni: Jesireeli, Iṣima, ati Idibaṣi. Orúkọ arabinrin wọn ni Haseleliponi. Penueli ni baba Gedori. Eseri bí Huṣa. Àwọn ni ọmọ Huri, àkọ́bí Efurata, tí ó jẹ́ baba Bẹtilẹhẹmu.