I. Kro 10

10
Ikú Saulu Ọba
(I. Sam 31:1-13)
1AWỌN ara Filistia si ba Israeli jagun, awọn ọkunrin Israeli si sá niwaju awọn ara Filistia, nwọn fi ara pa, nwọn si ṣubu li òke Gilboa.
2Awọn ara Filistia si lepa Saulu kikan, ati awọn ọmọ rẹ̀: awọn ara Filistia si pa Jonatani, ati Abinadabu, ati Melkiṣua, awọn ọmọ Saulu.
3Ogun na si le fun Saulu, awọn tafàtafà si ba a, on si damu nitori awọn tafàtafà.
4Nigbana ni Saulu wi fun ẹniti o ru ihamọra rẹ̀ pe, Fa idà rẹ yọ, ki o si fi gun mi, ki awọn alaikọla wọnyi ki o má ba wá fi mi ṣẹsin. Ṣugbọn ẹniti o ru ihamọra rẹ̀ kọ̀, nitori ẹ̀ru ba a gidigidi. Bẹ̃ni Saulu si mu idà, o si ṣubu le e.
5Nigbati ẹniti o ru ihamọra rẹ̀ si ri pe Saulu kú, on na pẹlu si ṣubu le idà rẹ̀, o si kú.
6Bẹ̃ni Saulu kú, ati awọn ọmọ rẹ̀ mẹtẹta, gbogbo ile rẹ̀ si kú ṣọkan.
7Nigbati gbogbo awọn ọkunrin Israeli ti o wà ni pẹtẹlẹ ri pe nwọn sá, ati pe Saulu ati awọn ọmọ rẹ̀ kú, nwọn fi ilu wọn silẹ, nwọn si sá: awọn ara Filistia si wá; nwọn si joko ninu wọn.
8O si ṣe ni ijọ keji, nigbati awọn ara Filistia de lati wá bọ́ awọn okú li aṣọ, nwọn si ri Saulu pẹlu, ati awọn ọmọ rẹ̀ pe; nwọn ṣubu li òke Gilboa.
9Nwọn si bọ́ ọ li aṣọ, nwọn si gbé ori rẹ̀ ati ihamọra rẹ̀, nwọn si ranṣẹ si awọn ara Filistia yika, lati mu ihin lọ irò fun awọn ere wọn, ati fun awọn enia.
10Nwọn si fi ihamọra rẹ̀ sinu ile oriṣa wọn, nwọn si kan agbari rẹ̀ mọ ile Dagoni.
11Nigbati gbogbo Jabeṣ-gileadi gbọ́ gbogbo eyi ti awọn ara Filistia ti ṣe si Saulu,
12Nwọn dide, gbogbo awọn ọkunrin ogun, nwọn si gbé okú Saulu lọ, ati okú awọn ọmọ rẹ̀, nwọn wá si Jabeṣi, nwọn si sìn egungun wọn labẹ igi oaku ni Jabeṣi, nwọn si gbawẹ ni ijọ meje.
13Bẹ̃ni Saulu kú ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o da si Oluwa, nitori ọ̀rọ Oluwa, ti on kò kiyesi, ati pẹlu nitori o lọ bère ọ̀ràn lọwọ abokusọrọ, lati ṣe ibere.
14Kò si bère lọwọ Oluwa; nitorina li o ṣe pa a, o si yi ijọba na pada sọdọ Dafidi ọmọ Jesse.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. Kro 10: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀