I. Kro 11

11
Dafidi Jọba lórí Israẹli ati Juda
(II. Sam 5:1-10)
1NIGBANA ni gbogbo Israeli ko ara wọn jọ si ọdọ Dafidi ni Hebroni, wipe, Kiyesi i, egungun rẹ ati ẹran ara rẹ li awa iṣe.
2Ati pẹlu li atijọ, ani nigbati Saulu jẹ ọba, iwọ li o nmu Israeli jade ti o si nmu u wá ile: Oluwa Ọlọrun rẹ si wi fun ọ pe, Ki iwọ ki o bọ Israeli, enia mi, ki iwọ ki o si ṣe ọmọ-alade lori Israeli enia mi.
3Nitorina ni gbogbo awọn agbagba Israeli ṣe tọ ọba wá ni Hebroni; Dafidi si ba wọn da majẹmu ni Hebroni niwaju Oluwa; nwọn si fi ororo yan Dafidi li ọba lori Israeli, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa nipa ọwọ Samueli.
4Ati Dafidi ati gbogbo Israeli jade lọ si Jerusalemu, ti iṣe Jebusi; awọn Jebusi ara ilẹ na ngbe ibẹ̀.
5Awọn ara ilu Jebusi si wi fun Dafidi pe, Iwọ kò gbọdọ wọ̀ ihinyi wa. Ṣugbọn Dafidi kó ilu odi Sioni ti iṣe ilu Dafidi.
6Dafidi si wipe, Ẹnikẹni ti o ba tetekọ kọlù awọn ara Jebusi ni yio ṣe olori ati balogun. Bẹ̃ni Joabu ọmọ Seruiah si tetekọ gòke lọ, o si jẹ olori.
7Dafidi si ngbe inu ilu odi, nitorina ni nwọn fi npè e ni ilu Dafidi.
8O si kọ́ ilu na yikakiri; ani lati Millo yikakiri: Joabu si tun iyokù ilu na ṣe.
9Bẹ̃ni Dafidi nga, o si npọ̀ si i: nitori ti Oluwa awọn ọmọ-ogun wà pẹlu rẹ̀.
Àwọn Ọmọ Ogun Dafidi tí Wọ́n Jẹ́ Olókìkí
(II. Sam 23:8-39)
10Wọnyi si ni olori awọn ọkunrin akọni ti Dafidi ni; awọn ti o fi ara wọn mọ ọ girigiri ni ijọba rẹ̀, pẹlu gbogbo Israeli, lati fi i jọba, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa fun Israeli.
11Eyi ni iye awọn ọkunrin akọni ti Dafidi ni; Jaṣobeamu ọmọ Hakmoni, olori ninu awọn ọgbọ̀n balogun: on li o gbé ọ̀kọ rẹ̀ soke si ọ̃dunrun enia ti o pa lẹrikan.
12Lẹhin rẹ̀ ni Eleaseri ọmọ Dodo, ara Ahohi, ẹniti iṣe ọkan ninu awọn akọni mẹta.
13On wà pẹlu Dafidi ni Pasdammimu, nigbati awọn ara Filistia ko ara wọn jọ lati jagun, nibiti ilẹ-bĩri kan wà ti o kún fun ọkà barli; awọn enia si salọ kuro niwaju awọn ara Filistia.
14Nwọn si duro jẹ li ãrin ilẹ-bĩri na, nwọn si gbà a, nwọn si pa awọn ara Filistia; Oluwa si fi igbala nla gbà wọn.
15Awọn mẹta ninu awọn ọgbọ̀n balogun si sọ̀kalẹ tọ̀ Dafidi lọ sibi apata na, ninu iho Adullamu; ogun ara Filistia si do li afonifoji Refaimu.
16Dafidi si mbẹ ninu ilu odi nigbana, ẹgbẹ-ogun awọn ara Filistia si mbẹ ni Betlehemu li akoko na.
17Dafidi si pòngbẹ, o si wipe, Emi iba ri ẹni fun mi mu ninu omi kanga Betlehemu ti mbẹ leti ẹnu-bodè!
18Awọn mẹta na si la inu ogun awọn ara Filistia kọja, nwọn si fa omi jade lati inu kanga Betlehemu, lati ẹnu-bodè, nwọn gbé e, nwọn si mu u tọ̀ Dafidi wá: Dafidi kò si fẹ mu u, ṣugbọn o tu u silẹ fun Oluwa,
19O si wipe, Ki Ọlọrun mi má jẹ ki emi ki o ṣe eyi: ki emi ki o ha mu ẹ̀jẹ awọn ọkunrin wọnyi, ti nwọn fi ẹmi wọn wewu? nipa ẹmi wọn ni nwọn fi mu u wá. Nitorina ni on kò ṣe fẹ mu u, nkan wọnyi li awọn akọni mẹta wọnyi ṣe.
20Ati Abiṣai arakunrin Joabu, on li olori ninu awọn mẹta: nitoriti o gbé ọ̀kọ rẹ̀ soke si ọ̃dunrun o pa wọn, o si ni orukọ ninu awọn mẹta.
21O ni ọla jù awọn mẹta ẹgbẹ ekeji lọ o si jẹ olori wọn: ṣugbọn kò to awọn mẹta iṣaju.
22Benaiah, ọmọ Jehoiada, ọmọ akọni ọkunrin kan ti Kabseeli, ẹniti o pọ̀ ni iṣe agbara, o pa awọn ọmọ Arieli meji ti Moabu; on sọkalẹ, o si pa kiniun kan ninu iho lakoko sno.
23O si pa ara Egipti kan, ọkunrin ti o si sigbọnlẹ igbọnwọ marun ni gigun rẹ̀; ati li ọwọ ara Egipti na ni ọ̀kọ kan wà bi idabu igi awunṣọ; o si sọ̀kalẹ tọ ọ lọ pẹlu ọpa, a si já ọ̀kọ li ọwọ ara Egipti na, o si fi ọ̀kọ rẹ̀ pa a.
24Nkan wọnyi ni Benaiah ọmọ Jehoiada ṣe, o si li orukọ ninu awọn akọni mẹta.
25Kiyesi i, o li ọla jù awọn ọ̀gbọn lọ, ṣugbọn kò to awọn mẹta iṣaju. Dafidi si fi ṣe olori awọn igbimọ ile rẹ̀.
26Awọn akọni ọkunrin ọmọ ogun rẹ̀ ni Asaheli arakunrin Joabu, Elhanani, ọmọ Dodo, ara Betlehemu.
27Sammotu, ara Harori, Helesi, ara Peloni,
28Ira, ọmọ Ikkeṣi, ara Tekoa, Abieseri ara Anatoti,
29Sibbekai, ara Husa, Ilai, ara Ahohi,
30Maharai, ara Netofa, Heledi ọmọ Baana, ara Netofa.
31Itai ọmọ Ribai ti Gibea, ti awọn ọmọ Benjamini, Benaiah ara Piratoni,
32Hurai ti odò Gaaṣi, Abieli ara Arbati,
33Asmafeti ara Baharumi, Eliaba ara Ṣaalboni.
34Awọn ọmọ Haṣemu ara Gisoni, Jonatani ọmọ Sage, ara Harari.
35Ahihamu ọmọ Sakari, ara Harari, Elifali ọmọ Uri,
36Heferi ara Mekerati, Ahijah ara Peloni,
37Hesro ara Karmeli, Naari ọmọ Esbai,
38Joeli arakunrin Natani, Mibhari ọmọ Haggeri,
39Saleki ara Ammoni, Naharai ara Beroti, ẹniti nru ihamọra Joabu ọmọ Seruiah,
40Ira ara Itri, Garobu ara Itri,
41Uriah ara Heti, Sabadi ọmọ Ahalai,
42Adina ọmọ Ṣisa ara Reubeni, olori awọn ara Reubeni, ati ọgbọ̀n enia pẹlu rẹ̀.
43Hanani ọmọ Maaka, ati Jehoṣafati ara Mitini,
44Ussia ara Aslerati, Ṣama ati Jegieli, awọn ọmọ Hotani, ara Aroeri,
45Jediaeli ọmọ Simri, ati Joha arakunrin rẹ̀ ara Tisi,
46Elieli ara Mahafi, ati Jeribai, ati Joṣafia, awọn ọmọ Elnaamu, ati Tima ara Moabu.
47Elieli, ati Obedi, ati Jasieli ara Mesobah.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. Kro 11: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀