I. Kro 9

9
Àwọn tí wọ́n dé láti Oko Ẹrú Babilonii
1A si ka iye gbogbo Israeli ni idile idile wọn; si kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe awọn ọba Israeli: Juda li a si kó lọ si Babiloni nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀.
2Awọn ti o tetekọ gbe ilẹ ini wọn, ati ilu wọn li awọn ọmọ Israeli, awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi ati awọn Netinimu.
3Ni Jerusalemu ni, ninu awọn ọmọ Juda, ati ninu awọn ọmọ Benjamini, ati ninu awọn ọmọ Efraimu, ati Manasse ngbe;
4Utai ọmọ Ammihudi, ọmọ Omri, ọmọ Imri, ọmọ Bani, ninu awọn ọmọ Faresi ọmọ Juda.
5Ati ninu awọn ara Ṣilo, Asaiah akọbi, ati awọn ọmọ rẹ̀.
6Ati ninu awọn ọmọ Sera, Jegueli, ati awọn arakunrin wọn, ẹdẹgbẹrin o di mẹwa.
7Ati ninu awọn ọmọ Benjamini; Sallu, ọmọ Meṣullamu, ọmọ Hodafiah, ọmọ Senua.
8Ati Ibneiah ọmọ Jerohamu, ati Ela ọmọ Ussi, ọmọ Mikri, ati Meṣullamu ọmọ Ṣefatiah, ọmọ Regueli, ọmọ Ibniah;
9Ati awọn arakunrin wọn, gẹgẹ bi idile wọn ẹgbẹrun o din mẹrinlelogoji. Gbogbo awọn ọkunrin wọnyi ni olori ninu awọn baba ni ile baba wọn.
Àwọn Àlùfáàa tí wọn ń gbé Jerusalẹmu
10Ati ninu awọn alufa; Jedaiah, ati Jehoiaribu ati Jakini,
11Ati Asariah ọmọ Hilkiah, ọmọ Meṣullamu, ọmọ Sadoku, ọmọ Meraiotu, ọmọ Ahitubu olori ile Ọlọrun;
12Ati Adaiah ọmọ Jerohamu, ọmọ Paṣuri, ọmọ Malkijah, ati Maasai ọmọ Adieli, ọmọ Jasera, ọmọ Meṣullamu, ọmọ Meṣillemiti, ọmọ Immeri;
13Ati awọn arakunrin wọn olori ile baba wọn, ẹgbẹsan o din ogoji; awọn alagbara akọni ọkunrin fun iṣẹ ìsin ile Ọlọrun.
Àwọn Ọmọ Lefi tí wọn ń gbé Jerusalẹmu
14Ati ninu awọn ọmọ Lefi; Ṣemaiah ọmọ Haṣubu, ọmọ Asrikamu, ọmọ Haṣabiah, ninu awọn ọmọ Merari;
15Ati Bakbakkari, Hereṣi, ati Galali, ati Mattaniah ọmọ Mika, ọmọ Sikri, ọmọ Asafu;
16Ati Obadiah ọmọ Ṣemaiah, ọmọ Galali, ọmọ Jedutuni, ati Berekiah ọmọ Asa, ọmọ Elkanah, ti ngbe ileto awọn ara Netofa.
Àwọn Aṣọ́nà Tẹmpili tí wọn ń gbé Jerusalẹmu
17Awọn adena si ni Ṣallumu, ati Akkubu, ati Talmoni, ati Ahimani, ati awọn arakunrin wọn; Ṣallumu li olori;
18Titi di isisiyi awọn ti o duro li oju-ọ̀na ọba niha ilà-õrùn; adena ni wọn li ẹgbẹ awọn ọmọ Lefi.
19Ati Ṣallumu ọmọ Kore, ọmọ Ebiasafu, ọmọ Kora, ati awọn arakunrin rẹ̀, ti ile baba rẹ̀, awọn ọmọ Kora, ni mbẹ lori iṣẹ ìsin na, olutọju iloro agọ na; awọn baba wọn ti mbẹ lori ibudo Oluwa ti nwọn ima ṣọ atiwọ̀le na.
20Ati Finehasi ọmọ Eleasari ni olori lori wọn ni igba atijọ, Oluwa si wà pẹlu rẹ̀.
21Sekariah ọmọ Meṣelemiah ni adena ilẹkun agọ ajọ enia.
22Gbogbo wọnyi ti a ti yàn lati ṣe adena loju iloro, jẹ igba o le mejila. A ka awọn wọnyi nipa idile wọn ni ileto wọn, awọn ẹniti Dafidi ati Samueli, ariran, ti yàn nitori otitọ wọn.
23Bẹ̃li awọn wọnyi ati awọn ọmọ wọn nṣẹ abojuto iloro ile Oluwa, eyini ni ile agọ na fun iṣọ.
24Ni igun mẹrẹrin ni awọn adena mbẹ, niha ilà-õrùn, ìwọ-õrún, ariwa ati gusu.
25Ati awọn arakunrin wọn ngbe ileto wọn, lati ma wá pẹlu wọn ni ijọ ekeje lati igba de igba.
26Nitoriti awọn ọmọ Lefi wọnyi jẹ awọn olori adena mẹrin, nwọn si wà ninu iṣẹ na, nwọn si wà lori iyara ati ibi iṣura ile Ọlọrun.
27Nwọn a si ma sùn yi ile Ọlọrun ka, nitori ti nwọn ni itọju na, ati ṣiṣi rẹ̀ li orowurọ jẹ ti wọn.
Àwọn Ọmọ Lefi Yòókù
28Ati awọn kan ninu wọn ni itọju ohun elo ìsin, lati ma kó wọn sinu ile ati si ode ni iye.
29Ninu wọn li a yàn lati ma bojuto ohun elo, ati gbogbo ohun elo ibi mimọ́, ati iyẹfun kikunna, ati ọti-waini, ati ororo, ati ojia, ati turari.
30Ati omiran ninu awọn ọmọ awọn alufa si fi turari ṣe ororo.
31Ati Mattitiah, ọkan ninu awọn ọmọ Lefi, ti iṣe akọbi Ṣallumu ọmọ Kora, li o nṣe alabojuto iṣẹ ohun ti a ndín.
32Ati ninu awọn arakunrin wọn ninu awọn ọmọ Kohati li o nṣe itọju akara-ifihan, lati mã pese rẹ̀ li ọjọjọ isimi.
33Wọnyi si li awọn akọrin, olori awọn baba awọn ọmọ Lefi, nwọn kò ni iṣẹ ninu iyara wọnni; nitori ti nwọn wà lẹnu iṣẹ wọn lọsan ati loru.
34Awọn wọnyi ni olori baba awọn ọmọ Lefi, ni iran wọn, olori ni nwọn: awọn wọnyi ni ngbe Jerusalemu.
Àwọn Baba Ńlá ati Àwọn Àtìrandíran Saulu Ọba
(8:29-38)
35Ati ni Gibeoni ni baba Gibeoni ngbe, Jegieli, orukọ aya ẹniti ijẹ Maaka.
36Akọbi ọmọ rẹ̀ si ni Abdoni, ati Suri ati Kiṣi, ati Baali, ati Neri, ati Nadabu,
37Ati Gedori, ati Ahio, ati Sekariah ati Mikloti.
38Mikloti si bi Ṣimeamu. Awọn wọnyi si mba awọn arakunrin wọn gbe ni Jerusalemu, kọju si awọn arakunrin wọn.
39Neri si bi Kiṣi, Kiṣi si bi Saulu, Saulu si bi Jonatani, ati Malkiṣua, ati Abinadabu, ati Eṣbaali.
40Ati ọmọ Jonatani ni Merib-baali; Merib-baali si bi Mika.
41Ati awọn ọmọ Mika ni Pitoni, ati Meleki, ati Tarea, ati Ahasi.
42Ahasi si bi Jara; Jara si bi Alemeti, ati Asmafeti, ati Simri, Simri si bi Mosa,
43Mosa si bi Binea, ati Refaiah ọmọ rẹ̀, Eleasa ọmọ rẹ̀, Aseli ọmọ rẹ̀.
44Aseli si bi ọmọ mẹfa, orukọ wọn ni wọnyi; Asrikamu, Bokeru, ati Iṣmaeli, ati Ṣeariah, ati Obadiah ati Hanani. Wọnyi li awọn ọmọ Aseli.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. Kro 9: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀