Mo sùn ṣugbọn ọkàn mi kò sùn.
Ẹ gbọ́! Olùfẹ́ mi ń kan ìlẹ̀kùn.
Ṣílẹ̀kùn fún mi,
arabinrin mi, olùfẹ́ mi,
àdàbà mi, olùfẹ́ mi tí ó péye,
nítorí pé, ìrì ti mú kí orí mi tutù,
gbogbo irun mi ti rẹ, fún ìrì alẹ́.
Mo ti bọ́ra sílẹ̀,
báwo ni mo ṣe lè tún múra?
Mo ti fọ ẹsẹ̀ mi,
báwo ni mo ṣe lè tún dọ̀tí rẹ̀?
Olùfẹ́ mi gbọ́wọ́ lé ìlẹ̀kùn,
ọkàn mi sì kún fún ayọ̀.
Mo dìde, mo ṣílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,
gbogbo ọwọ́ mi kún fún òjíá,
òróró òjíá sì ń kán ní ìka mi
sára kọ́kọ́rọ́ ìlẹ̀kùn.
Mo ṣílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,
ṣugbọn ó ti yipada, ó ti lọ.
Mo fẹ́rẹ̀ dákú, nígbà tí ó sọ̀rọ̀,
mo wá a, ṣugbọn n kò rí i,
mo pè é, ṣugbọn kò dáhùn.
Àwọn aṣọ́de rí mi
bí wọ́n ti ń rìn káàkiri ìlú;
wọ́n lù mí, wọ́n ṣe mí léṣe,
wọ́n sì gba ìborùn mi.
Mo rọ̀ yín, ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu,
bí ẹ bá rí olùfẹ́ mi,
ẹ bá mi sọ fún un pé:
Àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí.
Kí ni olùfẹ́ tìrẹ fi dára ju ti àwọn yòókù lọ?
Ìwọ arẹwà jùlọ láàrin àwọn obinrin?
Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju ti àwọn yòókù lọ?
Tí o fi ń kìlọ̀ fún wa bẹ́ẹ̀?
Olùfẹ́ mi lẹ́wà pupọ, ó sì pupa,
ó yàtọ̀ láàrin ẹgbaarun (10,000) ọkunrin.
Orí rẹ̀ dàbí ojúlówó wúrà,
irun rẹ̀ lọ́, ó ṣẹ́ léra wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́
ó dúdú bíi kóró iṣin.
Ojú rẹ̀ dàbí àwọn àdàbà etí odò,
tí a fi wàrà wẹ̀, tí wọ́n tò sí bèbè odò.
Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ dàbí ebè òdòdó olóòórùn dídùn,
tí ń tú òórùn dídùn jáde.
Ètè rẹ̀ dàbí òdòdó lílì,
tí òróró òjíá ń kán níbẹ̀.
Ọwọ́ rẹ̀ dàbí ọ̀pá wúrà,
tí a to ohun ọ̀ṣọ́ sí lára.
Ara rẹ̀ dàbí eyín erin tí ń dán
tí a fi òkúta safire bò.
Ẹsẹ̀ rẹ̀ dàbí òpó alabasita
tí a gbé ka orí ìtẹ́lẹ̀ wúrà.
Ìrísí rẹ̀ dàbí òkè Lẹbanoni, ó rí gbọ̀ngbọ̀nràn bí igi Kedari.
Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ dùn, àfi bí oyin,
ó wuni lọpọlọpọ.
Ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu,
òun ni olùfẹ́ mi, òun sì ni ọ̀rẹ́ mi