ORIN SOLOMONI 5

5
1Mo wọ inú ọgbà mi,
arabinrin mi, iyawo mi.
Mo kó òjíá ati àwọn turari olóòórùn dídùn mi jọ,
mo jẹ afárá oyin mi, pẹlu oyin inú rẹ̀,
mo mu waini mi ati wàrà mi.
Obinrin
Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ẹ jẹ, kí ẹ sì mu,
ẹ mu àmutẹ́rùn, ẹ̀yin olùfẹ́.
Orin Kẹrin
Obinrin
2Mo sùn ṣugbọn ọkàn mi kò sùn.
Ẹ gbọ́! Olùfẹ́ mi ń kan ìlẹ̀kùn.
Ọkunrin
Ṣílẹ̀kùn fún mi,
arabinrin mi, olùfẹ́ mi,
àdàbà mi, olùfẹ́ mi tí ó péye,
nítorí pé, ìrì ti mú kí orí mi tutù,
gbogbo irun mi ti rẹ, fún ìrì alẹ́.
Obinrin
3Mo ti bọ́ra sílẹ̀,
báwo ni mo ṣe lè tún múra?
Mo ti fọ ẹsẹ̀ mi,
báwo ni mo ṣe lè tún dọ̀tí rẹ̀?
4Olùfẹ́ mi gbọ́wọ́ lé ìlẹ̀kùn,
ọkàn mi sì kún fún ayọ̀.
5Mo dìde, mo ṣílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,
gbogbo ọwọ́ mi kún fún òjíá,
òróró òjíá sì ń kán ní ìka mi
sára kọ́kọ́rọ́ ìlẹ̀kùn.
6Mo ṣílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,
ṣugbọn ó ti yipada, ó ti lọ.
Mo fẹ́rẹ̀ dákú, nígbà tí ó sọ̀rọ̀,
mo wá a, ṣugbọn n kò rí i,
mo pè é, ṣugbọn kò dáhùn.
7Àwọn aṣọ́de rí mi
bí wọ́n ti ń rìn káàkiri ìlú;
wọ́n lù mí, wọ́n ṣe mí léṣe,
wọ́n sì gba ìborùn mi.
8Mo rọ̀ yín, ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu,
bí ẹ bá rí olùfẹ́ mi,
ẹ bá mi sọ fún un pé:
Àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí.
Àwọn Obinrin
9Kí ni olùfẹ́ tìrẹ fi dára ju ti àwọn yòókù lọ?
Ìwọ arẹwà jùlọ láàrin àwọn obinrin?
Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju ti àwọn yòókù lọ?
Tí o fi ń kìlọ̀ fún wa bẹ́ẹ̀?
Obinrin
10Olùfẹ́ mi lẹ́wà pupọ, ó sì pupa,
ó yàtọ̀ láàrin ẹgbaarun (10,000) ọkunrin.
11Orí rẹ̀ dàbí ojúlówó wúrà,
irun rẹ̀ lọ́, ó ṣẹ́ léra wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́
ó dúdú bíi kóró iṣin.
12Ojú rẹ̀ dàbí àwọn àdàbà etí odò,
tí a fi wàrà wẹ̀, tí wọ́n tò sí bèbè odò.
13Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ dàbí ebè òdòdó olóòórùn dídùn,
tí ń tú òórùn dídùn jáde.
Ètè rẹ̀ dàbí òdòdó lílì,
tí òróró òjíá ń kán níbẹ̀.
14Ọwọ́ rẹ̀ dàbí ọ̀pá wúrà,
tí a to ohun ọ̀ṣọ́ sí lára.
Ara rẹ̀ dàbí eyín erin tí ń dán
tí a fi òkúta safire bò.
15Ẹsẹ̀ rẹ̀ dàbí òpó alabasita
tí a gbé ka orí ìtẹ́lẹ̀ wúrà.
Ìrísí rẹ̀ dàbí òkè Lẹbanoni, ó rí gbọ̀ngbọ̀nràn bí igi Kedari.
16Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ dùn, àfi bí oyin,
ó wuni lọpọlọpọ.
Ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu,
òun ni olùfẹ́ mi, òun sì ni ọ̀rẹ́ mi,
Àwọn Obinrin

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN SOLOMONI 5: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀