ORIN SOLOMONI 4

4
1Wò ó! O dára gan-an ni, olólùfẹ́ mi,
ẹwà rẹ pọ̀.
Ẹyinjú rẹ dàbí ti àdàbà lábẹ́ ìbòjú rẹ,
irun orí rẹ dàbí ọ̀wọ́ ewúrẹ́,
tí wọn ń sọ̀kalẹ̀ láti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Gileadi.
2Eyín rẹ dàbí ọ̀wọ́ aguntan tí wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ gé irun wọn,
tí wọn wá fọ̀;
gbogbo wọn gún régé,
Kò sí ọ̀kan kan tí ó yọ ninu wọn.
3Ètè rẹ dàbí òwú pupa;
ẹnu rẹ fanimọ́ra,
ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ ń dán bí ìlàjì èso Pomegiranate,
lábẹ́ ìbòjú rẹ.
4Ọrùn rẹ dàbí ilé ìṣọ́ Dafidi,
tí a kọ́ fún ihamọra,
ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ dàbí ẹgbẹrun (1000) asà tí a kó kọ́,
bí apata àwọn akọni jagunjagun tí a kó jọ.
5Ọmú rẹ mejeeji dàbí ọmọ àgbọ̀nrín meji, tí wọn jẹ́ ìbejì,
tí wọn ń jẹko láàrin òdòdó lílì.
6N óo wà lórí òkè òjíá,
ati lórí òkè turari,
títí ilẹ̀ yóo fi mọ́,
tí òkùnkùn yóo sì lọ.
7O dára gan-an ni, olùfẹ́ mi!
O dára dára, o ò kù síbìkan,
kò sí àbààwọ́n kankan lára rẹ.
8Máa bá mi bọ̀ láti òkè Lẹbanoni, iyawo mi,
máa bá mi bọ̀ láti òkè Lẹbanoni.
Kúrò ní ṣóńṣó òkè Amana,
kúrò lórí òkè Seniri ati òkè Herimoni,
kúrò ninu ihò kinniun, ati ibi tí àwọn ẹkùn ń gbé.
9O ti kó sí mi lẹ́mìí, arabinrin mi, iyawo mi,
ẹ̀ẹ̀kan náà tí o ti ṣíjú wò mí,
pẹlu nǹkan ọ̀ṣọ́ tí ó wà lọ́rùn rẹ,
ni o ti kó sí mi lórí.
10Ìfẹ́ rẹ ti dùn tó! Arabinrin mi, iyawo mi,
ìfẹ́ rẹ dùn ju waini lọ.
Òróró ìkunra rẹ dára ju turari-kí-turari lọ.
11Oyin ní ń kán ní ètè rẹ, iyawo mi,
wàrà ati oyin wà lábẹ́ ahọ́n rẹ,
òórùn dídùn aṣọ rẹ dàbí òórùn Lẹbanoni.
12Arabinrin mi dàbí ọgbà tí a ti ti ìlẹ̀kùn rẹ̀.
Ọgbà tí a tì ni iyawo mi;
àní orísun omi tí a tì ni ọ́.
13Àwọn ohun ọ̀gbìn inú rẹ tí ń sọ dàbí ọgbà pomegiranate,
tí ó kún fún èso tí ó dára jùlọ,
àwọn bíi igi hena ati nadi;
14igi nadi ati Safironi, Kalamusi ati Sinamoni,
pẹlu oríṣìíríṣìí igi turari,
igi òjíá, ati ti aloe,
ati àwọn ojúlówó turari tí òórùn wọn dára jùlọ.
15Ọgbà tí ó ní orísun omi ni ọ́,
kànga omi tútù,
àní, odò tí ń ṣàn, láti òkè Lẹbanoni.
Obinrin
16Dìde, ìwọ afẹ́fẹ́ ìhà àríwá,
máa bọ̀, ìwọ afẹ́fẹ́ ìhà gúsù!
Fẹ́ sórí ọgbà mi,
kí òórùn dídùn rẹ̀ lè tàn káàkiri.
Kí olùfẹ́ mi wá sinu ọgbà rẹ̀,
kí ó sì jẹ èso tí ó bá dára jùlọ.
Ọkunrin

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN SOLOMONI 4: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀