ORIN SOLOMONI 3

3
1Mo wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́,
lórí ibùsùn mi lálẹ́,
mo wá a, ṣugbọn n kò rí i;
mo pè é, ṣugbọn kò dáhùn.
2N óo dìde nisinsinyii, n óo sì lọ káàkiri ìlú,
n óo wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́,
ní gbogbo òpópónà ati ní gbogbo gbàgede.
Mo wá a ṣugbọn n kò rí i.
3Àwọn aṣọ́de rí mi,
bí wọ́n ṣe ń lọ káàkiri ìlú.
Mo bèèrè lọ́wọ́ wọn pé,
“Ǹjẹ́ ẹ rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́?”
4Mo fẹ́rẹ̀ má tíì kúrò lọ́dọ̀ wọn,
ni mo bá rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́.
Mo dì í mú, n kò sì jẹ́ kí ó lọ,
títí tí mo fi mú un dé ilé ìyá mi,
ninu ìyẹ̀wù ẹni tí ó lóyún mi.
5Mò ń kìlọ̀ fun yín, ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu,
mo fi egbin ati àgbọ̀nrín inú igbó búra,
pé, ẹ kò gbọdọ̀ jí olùfẹ́ mi, títí yóo fi wù ú láti jí.
Orin Kẹta
Obinrin
6Kí ló ń jáde bọ̀ láti inú aṣálẹ̀ yìí,
tí ó dàbí òpó èéfín,
tí ó kún fún òórùn dídùn òjíá ati turari,
pẹlu òórùn dídùn àtíkè àwọn oníṣòwò?
7Wò ó! Solomoni ni wọ́n ń gbé bọ̀, lórí ìtẹ́ rẹ̀,
ọgọta akọni ọkunrin, lára àwọn akọni Israẹli,
ni ó yí ìtẹ́ rẹ̀ ká.
8Gbogbo wọn dira ogun pẹlu idà,
akọni sì ni wọ́n lójú ogun.
Olukuluku dira pẹlu idà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, nítorí ìdágìrì ọ̀gànjọ́.
9Igi Lẹbanoni ni Solomoni fi ṣe ìtẹ́ rẹ̀.
10Ó fi fadaka ṣe àwọn ẹsẹ̀ ìjókòó rẹ̀,
ó fi wúrà ṣe ẹ̀yìn rẹ̀,
Aṣọ elése-àlùkò tí àwọn ọmọbinrin Jerusalẹmu hun ni ó fi ṣe tìmùtìmù ìjókòó rẹ̀.
11Ẹ jáde lọ, ẹ̀yin ọmọbinrin Sioni,
ẹ lọ wo Solomoni ọba,
pẹlu adé tí ìyá rẹ̀ fi dé e lórí,
ní ọjọ́ igbeyawo,
ní ọjọ́ ìdùnnú ati ọjọ́ ayọ̀ rẹ̀.
Ọkunrin

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN SOLOMONI 3: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀