O. Sol 5:2-16

O. Sol 5:2-16 Yoruba Bible (YCE)

Mo sùn ṣugbọn ọkàn mi kò sùn. Ẹ gbọ́! Olùfẹ́ mi ń kan ìlẹ̀kùn. Ṣílẹ̀kùn fún mi, arabinrin mi, olùfẹ́ mi, àdàbà mi, olùfẹ́ mi tí ó péye, nítorí pé, ìrì ti mú kí orí mi tutù, gbogbo irun mi ti rẹ, fún ìrì alẹ́. Mo ti bọ́ra sílẹ̀, báwo ni mo ṣe lè tún múra? Mo ti fọ ẹsẹ̀ mi, báwo ni mo ṣe lè tún dọ̀tí rẹ̀? Olùfẹ́ mi gbọ́wọ́ lé ìlẹ̀kùn, ọkàn mi sì kún fún ayọ̀. Mo dìde, mo ṣílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi, gbogbo ọwọ́ mi kún fún òjíá, òróró òjíá sì ń kán ní ìka mi sára kọ́kọ́rọ́ ìlẹ̀kùn. Mo ṣílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi, ṣugbọn ó ti yipada, ó ti lọ. Mo fẹ́rẹ̀ dákú, nígbà tí ó sọ̀rọ̀, mo wá a, ṣugbọn n kò rí i, mo pè é, ṣugbọn kò dáhùn. Àwọn aṣọ́de rí mi bí wọ́n ti ń rìn káàkiri ìlú; wọ́n lù mí, wọ́n ṣe mí léṣe, wọ́n sì gba ìborùn mi. Mo rọ̀ yín, ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu, bí ẹ bá rí olùfẹ́ mi, ẹ bá mi sọ fún un pé: Àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí. Kí ni olùfẹ́ tìrẹ fi dára ju ti àwọn yòókù lọ? Ìwọ arẹwà jùlọ láàrin àwọn obinrin? Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju ti àwọn yòókù lọ? Tí o fi ń kìlọ̀ fún wa bẹ́ẹ̀? Olùfẹ́ mi lẹ́wà pupọ, ó sì pupa, ó yàtọ̀ láàrin ẹgbaarun (10,000) ọkunrin. Orí rẹ̀ dàbí ojúlówó wúrà, irun rẹ̀ lọ́, ó ṣẹ́ léra wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ ó dúdú bíi kóró iṣin. Ojú rẹ̀ dàbí àwọn àdàbà etí odò, tí a fi wàrà wẹ̀, tí wọ́n tò sí bèbè odò. Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ dàbí ebè òdòdó olóòórùn dídùn, tí ń tú òórùn dídùn jáde. Ètè rẹ̀ dàbí òdòdó lílì, tí òróró òjíá ń kán níbẹ̀. Ọwọ́ rẹ̀ dàbí ọ̀pá wúrà, tí a to ohun ọ̀ṣọ́ sí lára. Ara rẹ̀ dàbí eyín erin tí ń dán tí a fi òkúta safire bò. Ẹsẹ̀ rẹ̀ dàbí òpó alabasita tí a gbé ka orí ìtẹ́lẹ̀ wúrà. Ìrísí rẹ̀ dàbí òkè Lẹbanoni, ó rí gbọ̀ngbọ̀nràn bí igi Kedari. Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ dùn, àfi bí oyin, ó wuni lọpọlọpọ. Ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu, òun ni olùfẹ́ mi, òun sì ni ọ̀rẹ́ mi

O. Sol 5:2-16 Bibeli Mimọ (YBCV)

Emi sùn, ṣugbọn ọkàn mi ji, ohùn olufẹ mi ni nkànkun, wipe: Ṣilẹkun fun mi, arabinrin mi, olufẹ mi, adaba mi, alailabawọn mi: nitori ori mi kún fun ìri, ati ìdi irun mi fun kikán oru. Mo ti bọ́ awọtẹlẹ mi; emi o ti ṣe gbe e wọ̀? mo ti wẹ̀ ẹsẹ̀ mi; emi o ti ṣe sọ wọn di aimọ́? Olufẹ mi nawọ rẹ̀ lati inu ihò ilẹkùn, inu mi sì yọ si i. Emi dide lati ṣilẹkun fun olufẹ mi, ojia si nkán lọwọ mi, ati ojia olõrùn didùn ni ika mi sori idimu iṣikà. Mo ṣilẹkun fun olufẹ mi; ṣugbọn olufẹ mi ti fà sẹhin, o si ti lọ: aiya pá mi nigbati o sọ̀rọ, mo wá a, ṣugbọn emi kò ri i, mo pè e, ṣugbọn on kò da mi lohùn. Awọn oluṣọ ti nrìn ilu kiri ri mi, nwọn lù mi, nwọn sì ṣa mi lọgbẹ, awọn oluṣọ gbà iborùn mi lọwọ mi. Mo fi nyin bu, ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu, bi ẹnyin ba ri olufẹ mi, ki ẹ wi fun u pe, aisan ifẹ nṣe mi. Kini olufẹ rẹ jù olufẹ miran lọ, iwọ arẹwà julọ ninu awọn obinrin? kini olufẹ rẹ jù olufẹ miran ti iwọ fi nfi wa bú bẹ̃? Olufẹ mi funfun, o si pọn, on ni ọlá jù ọ̀pọlọpọ lọ. Ori rẹ̀ dabi wura ti o dara julọ, ìdi irun rẹ̀ dabi imọ̀ ọpẹ, o si du bi ẹiyẹ iwò. Oju rẹ̀ dabi àdaba li ẹba odò, ti a fi wàra wẹ̀, ti o si ngbe inu alafia. Ẹrẹ̀kẹ rẹ̀ dabi ebè turari, bi olõrùn didùn, ète rẹ̀ bi itanna lili, o nkán ojia olõrùn didùn. Ọwọ rẹ̀ dabi oruka wura ti o tò ni berili yika, ara rẹ̀ bi ehin-erin didán ti a fi saffire bò. Itan rẹ̀ bi ọwọ̀n marbili, ti a gbe ka ihò ìtẹbọ wura daradara; ìwo rẹ̀ dabi Lebanoni, titayọ rẹ̀ bi igi kedari. Ẹnu rẹ̀ dùn rekọja: ani o wunni patapata. Eyi li olufẹ mi, eyi si li ọrẹ mi, ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu.

O. Sol 5:2-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Mo ti sùn ṣùgbọ́n ọkàn mi jí. Gbọ́! Olólùfẹ́ mi ń kan ìlẹ̀kùn. “Ṣí i fún mi, arábìnrin mi, olùfẹ́ mi, àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi Orí mi kún fún omi ìrì, irun mi kún fún òtútù òru.” Mo ti bọ́ aṣọ ìgúnwà mi ṣé èmi gbọdọ̀ tún gbé e wọ̀? Mo ti wẹ ẹsẹ̀ mi ṣé èmi gbọdọ̀ tún tì í bọ eruku? Olùfẹ́ mi na ọwọ́ rẹ̀ láti inú ihò ìlẹ̀kùn inú mi sì yọ́ sí i Èmi dìde láti ṣílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi, òjìá bẹ̀rẹ̀ sí í kán ní ọwọ́ mi, òjìá olóòórùn ń ti ara ìka mi ń sàn sí orí ìdìmú ìlẹ̀kùn Èmi ṣí ìlẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi, ṣùgbọ́n olùfẹ́ mi ti kúrò, ó ti lọ ọkàn mi gbọgbẹ́ fún lílọ rẹ̀. Mo wá a kiri ṣùgbọ́n, n kò rí i. Mo pè é ṣùgbọ́n, kò dáhùn Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ ìlú rí mi bí wọ́n ti ṣe ń rìn yí ìlú ká. Wọ́n nà mí, wọ́n sá mi lọ́gbẹ́; wọ́n gba ìborùn mi lọ́wọ́ mi. Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ odi! Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu, mo bẹ̀ yín bí ẹ̀yin bá rí olùfẹ́ mi, kí ni ẹ̀yin yóò wí fún un? Ẹ wí fún un pé àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mi. Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tókù lọ, ìwọ arẹwà jùlọ láàrín àwọn obìnrin? Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tókù lọ tí ìwọ fi ń fi wá bú bẹ́ẹ̀? Olùfẹ́ mi ní ìtànṣán ó sì pọ́n ó ní ọlá ju ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ. Orí rẹ̀ rí bí i wúrà tí ó dára jùlọ ìdì irun rẹ̀ rí bí i imọ̀ ọ̀pẹ ó sì dúdú bí i ẹyẹ ìwò Ojú rẹ̀ rí bí i ti àdàbà ní ẹ̀bá odò tí ń sàn, tí a fi wàrà wẹ̀, tí ó jì, tí ó sì dákẹ́ rọ́rọ́ Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ rí bí ibùsùn tùràrí tí ó sun òórùn tùràrí dídùn Ètè rẹ̀ rí bí i ìtànná lílì ó ń kán òjìá olóòórùn dídùn Apá rẹ̀ rí bí i ọ̀pá wúrà, tí a to ohun ọ̀ṣọ́ sí yíká Ara rẹ̀ rí bí i eyín erin dídán tí a fi safire ṣe lọ́ṣọ̀ọ́. Ẹsẹ̀ rẹ̀ rí bí i òpó mábù tí a gbé ka ihò ìtẹ̀bọ̀ wúrà dáradára Ìrísí rẹ̀ rí bí igi kedari Lebanoni, tí dídára rẹ̀ kò ní ẹgbẹ́. Ẹnu rẹ̀ jẹ́ adùn fún ara rẹ̀ ó wu ni pátápátá. Háà! Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu, Èyí ni olùfẹ́ mi, èyí sì ni ọ̀rẹ́ mi.