ROMU 8:1-25

ROMU 8:1-25 YCE

Nisinsinyii, kò sí ìdálẹ́bi kan mọ́ fún àwọn tí ó wà ní ìṣọ̀kan pẹlu Kristi Jesu. Ìdí ni pé, agbára Ẹ̀mí, tí ó ń fi ìyè fún àwọn tí ń bá Kristi gbé, ti dá mi nídè kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ati kúrò lábẹ́ àṣẹ ikú. Èyí jẹ́ nǹkan tí kò ṣe é ṣe lábẹ́ Òfin, nítorí eniyan kò lè ṣàì dẹ́ṣẹ̀. Ṣugbọn Ọlọrun ti ṣe é, nígbà tí ó dá ẹ̀bi ikú fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ ninu ẹ̀yà ara eniyan. Àní sẹ́, Ọlọrun rán Ọmọ rẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí eniyan ẹlẹ́ṣẹ̀ láti pa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́. Ọlọrun ṣe èyí kí á lè tẹ̀lé ìlànà Òfin ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, àní àwa tí ìhùwàsí wa kì í ṣe bíi tí ẹni tí ẹran-ara ń lò ṣugbọn bí àwọn ẹni tí Ẹ̀mí ń darí. Nítorí àwọn tí ó ń hùwà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ẹran- ara ń lò a máa lépa ìtẹ́lọ́rùn fún ẹran-ara; ṣugbọn àwọn tí Ẹ̀mí ń darí a máa lépa àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí. Lílépa àwọn nǹkan ti ẹran-ara nìkan a máa yọrí sí ikú, ṣugbọn lílépa àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí a máa fúnni ní ìyè ati alaafia. Ìdí nìyí tí àwọn tí ń lépa nǹkan ti ẹran-ara nìkan fi jẹ́ ọ̀tá Ọlọrun, nítorí àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò lè fara wọn sábẹ́ àṣẹ Ọlọrun; wọn kò tilẹ̀ lè ṣe é rárá ni. Àwọn tí ń ṣe ìfẹ́ ẹran-ara wọn kò lè sin Ọlọrun. Ṣugbọn ní tiyín, ẹ kò hùwà gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ẹran-ara ń darí mọ́; Ẹ̀mí ló ń ṣamọ̀nà yín, bí Ẹ̀mí Ọlọrun bá ń gbé inú yín nítòótọ́. Nítorí pé ẹnikẹ́ni tí kò bá ní Ẹ̀mí Kristi ninu rẹ̀, kì í ṣe ti Kristi. Ṣugbọn bí Kristi bá ń gbé inú yín, bí ara yín yóo tilẹ̀ kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀, sibẹ ẹ̀mí yín yóo wà láàyè nítorí pé Ọlọrun ti da yín láre. Ǹjẹ́ bí Ẹ̀mí Ọlọrun, ẹni tí ó jí Jesu dìde kúrò ninu òkú, bá ń gbé inú yín, òun náà tí ó jí Kristi dìde kúrò ninu òkú yóo sọ ara yín, tí yóo kú, di alààyè nípa Ẹ̀mí rẹ̀, tí ó ń gbé inú yín. Nítorí náà, ẹ̀yin ará, kò sí ohunkohun mọ́ tí ó mú wa ní túlààsì pé kí á máa hùwà gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ẹran-ara ń darí. Nítorí bí ẹ bá hùwà bí àwọn tí ẹran-ara ń darí, kíkú ni ẹ óo kú dandan. Ṣugbọn tí ẹ bá ń rìn lọ́nà ti Ẹ̀mí, tí ẹ kò sì hu ìwà ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, ẹ óo yè. Nítorí àwọn tí Ẹ̀mí Ọlọrun bá ń darí ni ọmọ Ọlọrun. Ẹ̀mí tí Ọlọrun fun yín kì í ṣe èyí tí yóo tún sọ yín di ẹrú, tí yóo sì máa mu yín bẹ̀rù. Ṣugbọn Ẹ̀mí tí ó sọ yín di ọmọ ni ẹ gbà. Ẹ̀mí yìí náà ni ó jẹ́ kí á lè máa ké pe Ọlọrun pé, “Baba! Baba wa!” Ẹ̀mí kan náà ní ń sọ sí wa lọ́kàn pé ọmọ Ọlọrun ni wá. Wàyí ò, tí a bá jẹ́ ọmọ, ajogún ni wá. Tí a bá sì jẹ́ ajogún, a jẹ́ pé àwa pẹlu Kristi ni a óo jọ jogún pọ̀, bí a bá bá Kristi jìyà, a óo bá a gba iyì pẹlu. Mo wòye pé a kò lè fi ìyà ayé yìí wé ọlá tí Ọlọrun yóo dá wa ní ayé tí ń bọ̀ wá. Nítorí gbogbo ẹ̀dá ayé ló ń fi ìwàǹwára nàgà, tí wọn ń retí àkókò tí Ọlọrun yóo fi àwọn tíí ṣe ọmọ rẹ̀ hàn. Nítorí pé gbogbo ẹ̀dá ayé ló ti pasán, kì í ṣe pé ẹ̀dá ayé fúnra wọn ni wọ́n fẹ́ pasán, ṣugbọn bẹ́ẹ̀ ni ó wu Ẹlẹ́dàá láti yàn án. Sibẹ ìrètí ń bẹ pé: ẹ̀dá ayé pàápàá yóo bọ́ lóko ẹrú, kúrò ninu ipò ìdíbàjẹ́, yóo sì pín ninu ọlá àwọn ọmọ Ọlọrun. Àwa náà rí i pé, títí di òní olónìí, gbogbo ẹ̀dá ayé ni wọ́n ń jẹ̀rora, tí wọ́n sì ń rọbí bí aboyún. Ṣugbọn kì í ṣe ẹ̀dá ayé nìkan ló ń jẹ̀rora. Àní sẹ́, àwa fúnra wa, tí a ti rí Ẹ̀mí Ọlọrun gbà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn rẹ̀ àkọ́kọ́, à ń jẹ̀rora lọ́kàn wa, bí a ti ń retí àkókò tí Ọlọrun yóo pè wá lọ́mọ rẹ̀, tí yóo sì dá gbogbo ara wa nídè. Nítorí ti ìrètí yìí ni a fi gbà wá là. Ṣebí ohun tí a bá ti fojú rí ti kúrò ní ohun tí à ń retí. Àbí, ta ni í tún máa ń retí ohun tí ó bá ti rí? Ṣugbọn nígbà tí a bá ń retí ohun tí a kò ì tíì fojú rí, dídúró ni à á dúró dè é pẹlu ìfaradà títí yóo fi tẹ̀ wá lọ́wọ́.

Àwọn àwòrán ẹsẹ fún ROMU 8:1-25

ROMU 8:1-25 - Nisinsinyii, kò sí ìdálẹ́bi kan mọ́ fún àwọn tí ó wà ní ìṣọ̀kan pẹlu Kristi Jesu. Ìdí ni pé, agbára Ẹ̀mí, tí ó ń fi ìyè fún àwọn tí ń bá Kristi gbé, ti dá mi nídè kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ati kúrò lábẹ́ àṣẹ ikú. Èyí jẹ́ nǹkan tí kò ṣe é ṣe lábẹ́ Òfin, nítorí eniyan kò lè ṣàì dẹ́ṣẹ̀. Ṣugbọn Ọlọrun ti ṣe é, nígbà tí ó dá ẹ̀bi ikú fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ ninu ẹ̀yà ara eniyan. Àní sẹ́, Ọlọrun rán Ọmọ rẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí eniyan ẹlẹ́ṣẹ̀ láti pa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́. Ọlọrun ṣe èyí kí á lè tẹ̀lé ìlànà Òfin ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, àní àwa tí ìhùwàsí wa kì í ṣe bíi tí ẹni tí ẹran-ara ń lò ṣugbọn bí àwọn ẹni tí Ẹ̀mí ń darí. Nítorí àwọn tí ó ń hùwà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ẹran- ara ń lò a máa lépa ìtẹ́lọ́rùn fún ẹran-ara; ṣugbọn àwọn tí Ẹ̀mí ń darí a máa lépa àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí. Lílépa àwọn nǹkan ti ẹran-ara nìkan a máa yọrí sí ikú, ṣugbọn lílépa àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí a máa fúnni ní ìyè ati alaafia. Ìdí nìyí tí àwọn tí ń lépa nǹkan ti ẹran-ara nìkan fi jẹ́ ọ̀tá Ọlọrun, nítorí àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò lè fara wọn sábẹ́ àṣẹ Ọlọrun; wọn kò tilẹ̀ lè ṣe é rárá ni. Àwọn tí ń ṣe ìfẹ́ ẹran-ara wọn kò lè sin Ọlọrun.
Ṣugbọn ní tiyín, ẹ kò hùwà gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ẹran-ara ń darí mọ́; Ẹ̀mí ló ń ṣamọ̀nà yín, bí Ẹ̀mí Ọlọrun bá ń gbé inú yín nítòótọ́. Nítorí pé ẹnikẹ́ni tí kò bá ní Ẹ̀mí Kristi ninu rẹ̀, kì í ṣe ti Kristi. Ṣugbọn bí Kristi bá ń gbé inú yín, bí ara yín yóo tilẹ̀ kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀, sibẹ ẹ̀mí yín yóo wà láàyè nítorí pé Ọlọrun ti da yín láre. Ǹjẹ́ bí Ẹ̀mí Ọlọrun, ẹni tí ó jí Jesu dìde kúrò ninu òkú, bá ń gbé inú yín, òun náà tí ó jí Kristi dìde kúrò ninu òkú yóo sọ ara yín, tí yóo kú, di alààyè nípa Ẹ̀mí rẹ̀, tí ó ń gbé inú yín.
Nítorí náà, ẹ̀yin ará, kò sí ohunkohun mọ́ tí ó mú wa ní túlààsì pé kí á máa hùwà gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ẹran-ara ń darí. Nítorí bí ẹ bá hùwà bí àwọn tí ẹran-ara ń darí, kíkú ni ẹ óo kú dandan. Ṣugbọn tí ẹ bá ń rìn lọ́nà ti Ẹ̀mí, tí ẹ kò sì hu ìwà ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, ẹ óo yè. Nítorí àwọn tí Ẹ̀mí Ọlọrun bá ń darí ni ọmọ Ọlọrun. Ẹ̀mí tí Ọlọrun fun yín kì í ṣe èyí tí yóo tún sọ yín di ẹrú, tí yóo sì máa mu yín bẹ̀rù. Ṣugbọn Ẹ̀mí tí ó sọ yín di ọmọ ni ẹ gbà. Ẹ̀mí yìí náà ni ó jẹ́ kí á lè máa ké pe Ọlọrun pé, “Baba! Baba wa!” Ẹ̀mí kan náà ní ń sọ sí wa lọ́kàn pé ọmọ Ọlọrun ni wá. Wàyí ò, tí a bá jẹ́ ọmọ, ajogún ni wá. Tí a bá sì jẹ́ ajogún, a jẹ́ pé àwa pẹlu Kristi ni a óo jọ jogún pọ̀, bí a bá bá Kristi jìyà, a óo bá a gba iyì pẹlu.

Mo wòye pé a kò lè fi ìyà ayé yìí wé ọlá tí Ọlọrun yóo dá wa ní ayé tí ń bọ̀ wá. Nítorí gbogbo ẹ̀dá ayé ló ń fi ìwàǹwára nàgà, tí wọn ń retí àkókò tí Ọlọrun yóo fi àwọn tíí ṣe ọmọ rẹ̀ hàn. Nítorí pé gbogbo ẹ̀dá ayé ló ti pasán, kì í ṣe pé ẹ̀dá ayé fúnra wọn ni wọ́n fẹ́ pasán, ṣugbọn bẹ́ẹ̀ ni ó wu Ẹlẹ́dàá láti yàn án. Sibẹ ìrètí ń bẹ pé: ẹ̀dá ayé pàápàá yóo bọ́ lóko ẹrú, kúrò ninu ipò ìdíbàjẹ́, yóo sì pín ninu ọlá àwọn ọmọ Ọlọrun. Àwa náà rí i pé, títí di òní olónìí, gbogbo ẹ̀dá ayé ni wọ́n ń jẹ̀rora, tí wọ́n sì ń rọbí bí aboyún. Ṣugbọn kì í ṣe ẹ̀dá ayé nìkan ló ń jẹ̀rora. Àní sẹ́, àwa fúnra wa, tí a ti rí Ẹ̀mí Ọlọrun gbà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn rẹ̀ àkọ́kọ́, à ń jẹ̀rora lọ́kàn wa, bí a ti ń retí àkókò tí Ọlọrun yóo pè wá lọ́mọ rẹ̀, tí yóo sì dá gbogbo ara wa nídè. Nítorí ti ìrètí yìí ni a fi gbà wá là. Ṣebí ohun tí a bá ti fojú rí ti kúrò ní ohun tí à ń retí. Àbí, ta ni í tún máa ń retí ohun tí ó bá ti rí? Ṣugbọn nígbà tí a bá ń retí ohun tí a kò ì tíì fojú rí, dídúró ni à á dúró dè é pẹlu ìfaradà títí yóo fi tẹ̀ wá lọ́wọ́.ROMU 8:1-25 - Nisinsinyii, kò sí ìdálẹ́bi kan mọ́ fún àwọn tí ó wà ní ìṣọ̀kan pẹlu Kristi Jesu. Ìdí ni pé, agbára Ẹ̀mí, tí ó ń fi ìyè fún àwọn tí ń bá Kristi gbé, ti dá mi nídè kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ati kúrò lábẹ́ àṣẹ ikú. Èyí jẹ́ nǹkan tí kò ṣe é ṣe lábẹ́ Òfin, nítorí eniyan kò lè ṣàì dẹ́ṣẹ̀. Ṣugbọn Ọlọrun ti ṣe é, nígbà tí ó dá ẹ̀bi ikú fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ ninu ẹ̀yà ara eniyan. Àní sẹ́, Ọlọrun rán Ọmọ rẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí eniyan ẹlẹ́ṣẹ̀ láti pa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́. Ọlọrun ṣe èyí kí á lè tẹ̀lé ìlànà Òfin ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, àní àwa tí ìhùwàsí wa kì í ṣe bíi tí ẹni tí ẹran-ara ń lò ṣugbọn bí àwọn ẹni tí Ẹ̀mí ń darí. Nítorí àwọn tí ó ń hùwà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ẹran- ara ń lò a máa lépa ìtẹ́lọ́rùn fún ẹran-ara; ṣugbọn àwọn tí Ẹ̀mí ń darí a máa lépa àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí. Lílépa àwọn nǹkan ti ẹran-ara nìkan a máa yọrí sí ikú, ṣugbọn lílépa àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí a máa fúnni ní ìyè ati alaafia. Ìdí nìyí tí àwọn tí ń lépa nǹkan ti ẹran-ara nìkan fi jẹ́ ọ̀tá Ọlọrun, nítorí àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò lè fara wọn sábẹ́ àṣẹ Ọlọrun; wọn kò tilẹ̀ lè ṣe é rárá ni. Àwọn tí ń ṣe ìfẹ́ ẹran-ara wọn kò lè sin Ọlọrun.

Mo wòye pé a kò lè fi ìyà ayé yìí wé ọlá tí Ọlọrun yóo dá wa ní ayé tí ń bọ̀ wá. Nítorí gbogbo ẹ̀dá ayé ló ń fi ìwàǹwára nàgà, tí wọn ń retí àkókò tí Ọlọrun yóo fi àwọn tíí ṣe ọmọ rẹ̀ hàn. Nítorí pé gbogbo ẹ̀dá ayé ló ti pasán, kì í ṣe pé ẹ̀dá ayé fúnra wọn ni wọ́n fẹ́ pasán, ṣugbọn bẹ́ẹ̀ ni ó wu Ẹlẹ́dàá láti yàn án. Sibẹ ìrètí ń bẹ pé: ẹ̀dá ayé pàápàá yóo bọ́ lóko ẹrú, kúrò ninu ipò ìdíbàjẹ́, yóo sì pín ninu ọlá àwọn ọmọ Ọlọrun. Àwa náà rí i pé, títí di òní olónìí, gbogbo ẹ̀dá ayé ni wọ́n ń jẹ̀rora, tí wọ́n sì ń rọbí bí aboyún. Ṣugbọn kì í ṣe ẹ̀dá ayé nìkan ló ń jẹ̀rora. Àní sẹ́, àwa fúnra wa, tí a ti rí Ẹ̀mí Ọlọrun gbà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn rẹ̀ àkọ́kọ́, à ń jẹ̀rora lọ́kàn wa, bí a ti ń retí àkókò tí Ọlọrun yóo pè wá lọ́mọ rẹ̀, tí yóo sì dá gbogbo ara wa nídè. Nítorí ti ìrètí yìí ni a fi gbà wá là. Ṣebí ohun tí a bá ti fojú rí ti kúrò ní ohun tí à ń retí. Àbí, ta ni í tún máa ń retí ohun tí ó bá ti rí? Ṣugbọn nígbà tí a bá ń retí ohun tí a kò ì tíì fojú rí, dídúró ni à á dúró dè é pẹlu ìfaradà títí yóo fi tẹ̀ wá lọ́wọ́.