ORIN DAFIDI 86:5-7

ORIN DAFIDI 86:5-7 YCE

Nítorí pé olóore ni ọ́, OLUWA, o máa ń dárí jini; ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀ sí gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́. Fetí sí adura mi, OLUWA, gbọ́ igbe ẹ̀bẹ̀ mi. Ní ọjọ́ ìpọ́njú mo ké pè ọ́, nítorí pé o máa ń gbọ́ adura mi.