ORIN DAFIDI 76
76
Ọlọrun Ajàṣẹ́gun
1Àwọn ará Juda mọ Ọlọrun,
orúkọ rẹ̀ sì lọ́wọ̀ ní Israẹli.
2Ilé rẹ̀ wà ní Salẹmu,
ibùgbé rẹ̀ wà ní Sioni.
3Níbẹ̀ ni ó ti ṣẹ́ ọfà ọ̀tá tí ń rọ̀jò,
ati apata, ati idà, ati àwọn ohun ìjà ogun.
4Ológo ni ọ́, ọlá rẹ sì pọ̀,
ó ju ti àwọn òkè tí ó kún fún ẹran lọ.
5A gba ìkógun lọ́wọ́ àwọn akikanju,
wọ́n sun oorun àsùn-ùn-jí;
àwọn alágbára kò sì le gbé ọwọ́ láti jà.
6Nípa ìbáwí rẹ, Ọlọrun Jakọbu,
ati ẹṣin, ati ẹni tó gun ẹṣin,
gbogbo wọn ló ṣubú lulẹ̀, tí wọn kò sì lè mira.
7Ṣugbọn ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ni ọ́!
Ta ló tó dúró níwájú rẹ
tí ibinu rẹ bá dé?
8Láti ọ̀run wá ni o ti ń ṣe ìdájọ́,
ẹ̀rù ba ayé, ayé sì dúró jẹ́ẹ́;
9nígbà tí Ọlọrun dìde láti gbé ìdájọ́ kalẹ̀,
láti gba gbogbo àwọn tí à ń nilára láyé sílẹ̀.
10Dájúdájú ibinu eniyan yóo pada di ìyìn fún ọ;
àwọn tí wọ́n bá sì bọ́ lọ́wọ́ ibinu rẹ
yóo ṣe àjọ̀dún rẹ.
11Jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLUWA Ọlọrun rẹ, kí o sì mú un ṣẹ,
kí gbogbo àwọn tí ó yí i ká mú ẹ̀bùn wá
fún ẹni tí ó yẹ kí á bẹ̀rù.
12Ẹni tí ń gba ẹ̀mí àwọn ìjòyè,
tí ó ń ṣe ẹ̀rù ba àwọn ọba ayé.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ORIN DAFIDI 76: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010