ORIN DAFIDI 75

75
Ọlọrun Onídàájọ́
1A dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Ọlọrun; a dúpẹ́.
À ń kéde orúkọ rẹ,
a sì ń ròyìn iṣẹ́ ribiribi tí o ṣe.
2OLUWA ní, “Nígbà tí àkókò tí mo yà sọ́tọ̀ bá tó,
n óo ṣe ìdájọ́ pẹlu àìṣojúṣàájú.
3Nígbà tí ayé bá ń mì síhìn-ín sọ́hùn-ún,
ati gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀;
èmi a mú kí òpó rẹ̀ dúró wámúwámú.
4Èmi a sọ fún àwọn tí ń fọ́nnu pé, ‘Ẹ yé fọ́nnu’;
èmi a sì sọ fún àwọn eniyan burúkú pé, ‘Ẹ yé ṣe ìgbéraga.’
5Ẹ má halẹ̀ ju bí ó ti yẹ lọ,
ẹ má sì gbéraga.”
6Nítorí pé kì í ṣe láti ìlà oòrùn,
tabi láti ìwọ̀ oòrùn,
bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í ṣe apá gúsù tabi àríwá ni ìgbéga tií wá.
7Ọlọrun níí dájọ́ bí ó ti wù ú:
á rẹ ẹnìkan sílẹ̀, á sì gbé ẹlòmíràn ga.
8Ife kan wà ní ọwọ́ OLUWA,
Ibinu Oluwa ló kún inú rẹ̀,
ó ń ru bí ọtí àní bí ọtí tí a ti lú,
yóo ṣẹ́ ninu rẹ̀;
gbogbo àwọn eniyan burúkú ilẹ̀ ayé ni yóo sì mu ún,
wọn óo mu ún tán patapata tòun ti gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ rẹ̀.
9Ṣugbọn èmi óo máa yọ̀ títí lae,
n óo kọ orin ìyìn sí Ọlọrun Jakọbu.
10Ọlọrun yóo gba gbogbo agbára ọwọ́ àwọn eniyan burúkú kúrò;
ṣugbọn yóo fi agbára kún agbára fún àwọn olódodo.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 75: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀