ORIN DAFIDI 77

77
Ìtùnú ní Àkókò Ìpọ́njú
1Mo ké pe Ọlọrun fún ìrànlọ́wọ́,
mo kígbe pe Ọlọrun kí ó lè gbọ́ tèmi.
2Ní ọjọ́ ìpọ́njú mi, mo wá OLUWA;
ní òru, mo tẹ́wọ́ adura láìkáàárẹ̀,
ṣugbọn n kò rí ìtùnú.
3Mo ronú nípa Ọlọrun títí, mò ń kérora;
mo ṣe àṣàrò títí, ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì.
4OLUWA, o ò jẹ́ kí n dijú wò ní gbogbo òru
mo dààmú tóbẹ́ẹ̀ tí n kò le sọ̀rọ̀.
5Mo ranti ìgbà àtijọ́,
mo ranti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn.
6Mo ronú jinlẹ̀ lóru,
mo ṣe àṣàrò, mo yẹ ọkàn mi wò.
7Ṣé Ọlọrun yóo kọ̀ wá sílẹ̀ títí lae ni;
àbí inú rẹ̀ kò tún ní dùn sí wa mọ́?
8Ṣé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ti pin títí lae ni;
àbí ìlérí rẹ̀ ti dópin patapata?
9Ṣé Ọlọrun ti gbàgbé láti máa ṣoore ni;
àbí ó ti fi ibinu pa ojú àánú rẹ̀ dé?
10Nígbà náà ni mo wí pé, “Ohun tí ó bà mí lọ́kàn jẹ́ ni pé
Ọ̀gá Ògo kò jẹ́wọ́ agbára mọ́.”
11N óo ranti àwọn iṣẹ́ OLUWA,
àní, n óo ranti àwọn iṣẹ́ ìyanu ìgbàanì.
12N óo máa ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ;
n óo sì máa ronú lórí àwọn iṣẹ́ ribiribi tí o ṣe.
13Ọlọrun, mímọ́ ni ọ̀nà rẹ;
oriṣa wo ni ó tó Ọlọrun wa?
14Ìwọ ni Ọlọrun tí ń ṣe ohun ìyanu;
o ti fi agbára rẹ hàn láàrin àwọn eniyan.
15O ti fi agbára rẹ gba àwọn eniyan rẹ là;
àní, àwọn ọmọ Jakọbu ati Josẹfu.
16Nígbà tí omi òkun rí ọ, Ọlọrun,
àní, nígbà tí omi òkun fi ojú kàn ọ́,
ẹ̀rù bà á;
ibú omi sì wárìrì.
17Ìkùukùu da omi òjò sílẹ̀,
ojú ọ̀run sán ààrá;
mànàmáná ń kọ yẹ̀rì káàkiri.
18Ààrá ń sán kíkankíkan ní ojú ọ̀run,
mànàmáná ń kọ yànràn, gbogbo ayé sì mọ́lẹ̀;
ilẹ̀ ayé wárìrì, ó sì mì tìtì.
19Ọ̀nà rẹ wà lójú omi òkun,
ipa ọ̀nà rẹ la omi òkun ńlá já;
sibẹ ẹnìkan kò rí ipa ẹsẹ̀ rẹ.
20O kó àwọn eniyan rẹ jáde bí agbo ẹran,
o fi Mose ati Aaroni ṣe olórí wọn.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 77: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀