ORIN DAFIDI 73:25-28

ORIN DAFIDI 73:25-28 YCE

Ta ni mo ní lọ́run lẹ́yìn rẹ? Kò sì sí ohun kan tí ó wù mí láyé yìí bíkòṣe ìwọ. Àárẹ̀ lè mú ara ati ẹ̀mí mi, ṣugbọn Ọlọrun ni agbára ẹ̀mí mi, ati ìpín mi títí lae. Ó dájú pé àwọn tí ó jìnnà sí ọ yóo ṣègbé, o óo sì pa àwọn tí ó bá ṣe alaiṣootọ sí ọ run. Ní tèmi o, ó dára láti súnmọ́ Ọlọrun; mo ti fi ìwọ OLUWA Ọlọrun ṣe ààbò mi, kí n lè máa ròyìn gbogbo iṣẹ́ rẹ.