O. Daf 73:25-28
O. Daf 73:25-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ta ni mo ní ní ọ̀run, bí kò ṣe ìwọ? Àti ní ayé kò sí ohun tí mo fẹ́ lẹ́yìn rẹ. Ara mi àti ọkàn mi le è kùnà ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni agbára ẹ̀mí mi àti ìpín mi títí láé. Àwọn tí ó jìnnà sí ọ yóò ṣègbé ìwọ ti pa gbogbo wọn run; tí ń ṣe àgbèrè kiri kúrò lọ́dọ̀ rẹ Ṣùgbọ́n ní ti èmi, ó dára láti súnmọ́ Ọlọ́run Èmi ti fi OLúWA Olódùmarè ṣe ààbò mi; Kí èmi ó lè máa sọ̀rọ̀ iṣẹ́ rẹ.
O. Daf 73:25-28 Bibeli Mimọ (YBCV)
Tani mo ni li ọrun bikoṣe iwọ? kò si si ohun ti mo fẹ li aiye pẹlu rẹ. Ẹran-ara mi ati aiya mi di ãrẹ̀ tan: ṣugbọn Ọlọrun ni apata aiya mi, ati ipin mi lailai. Sa wò o, awọn ti o jina si ọ yio ṣegbe: iwọ ti pa gbogbo wọn run ti nṣe àgbere kiri kuro lọdọ rẹ. Ṣugbọn o dara fun mi lati sunmọ Ọlọrun: emi ti gbẹkẹ mi le Oluwa Ọlọrun, ki emi ki o le ma sọ̀rọ iṣẹ rẹ gbogbo.
O. Daf 73:25-28 Yoruba Bible (YCE)
Ta ni mo ní lọ́run lẹ́yìn rẹ? Kò sì sí ohun kan tí ó wù mí láyé yìí bíkòṣe ìwọ. Àárẹ̀ lè mú ara ati ẹ̀mí mi, ṣugbọn Ọlọrun ni agbára ẹ̀mí mi, ati ìpín mi títí lae. Ó dájú pé àwọn tí ó jìnnà sí ọ yóo ṣègbé, o óo sì pa àwọn tí ó bá ṣe alaiṣootọ sí ọ run. Ní tèmi o, ó dára láti súnmọ́ Ọlọrun; mo ti fi ìwọ OLUWA Ọlọrun ṣe ààbò mi, kí n lè máa ròyìn gbogbo iṣẹ́ rẹ.