ORIN DAFIDI 73

73
Ìdájọ́ Òdodo Ọlọrun
1Nítòótọ́ Ọlọrun ṣeun fún Israẹli,
ó ṣeun fún àwọn tí ọkàn wọn mọ́.
2Ṣugbọn, ní tèmi, mo fẹ́rẹ̀ yọ̀ ṣubú,
ẹsẹ̀ mi fẹ́rẹ̀ tàsé.
3Nítorí mò ń ṣe ìlara àwọn onigbeeraga
nígbà tí mo rí ọrọ̀ àwọn eniyan burúkú.
4Wọn kì í jẹ ìrora kankan,
ara wọn dá pé, ó sì jọ̀lọ̀.
5Wọn kì í ní wahala bí àwọn ẹlòmíràn;
ìyọnu tíí dé bá àwọn ẹlòmíràn kì í dé ọ̀dọ̀ wọn.
6Nítorí náà, wọn á kó ìgbéraga bọ ọrùn bí ẹ̀gbà,
wọn á fi ìwà ipá bora bí aṣọ.
7Wọ́n sanra tóbẹ́ẹ̀ tí ojú wọn yíbò;
èrò òmùgọ̀ sì kún ọkàn wọn ní àkúnwọ́sílẹ̀.
8Wọ́n ń pẹ̀gàn eniyan, wọ́n ń sọ̀rọ̀ pẹlu ìlara;
wọ́n sì ń fi ìgbéraga halẹ̀.
9Wọ́n ń fi ẹnu wọn sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọrun;
wọn a sì máa sọ̀rọ̀ ìgbéraga káàkiri ayé.
10Nítorí náà, àwọn eniyan á yipada, wọn á fara mọ́ wọn,
wọn á máa yìn wọ́n, láìbìkítà fún ibi tí wọn ń ṣe.
11Wọn á máa wí pé, “Báwo ni Ọlọrun ṣe lè mọ̀?
Ǹjẹ́ Ọ̀gá Ògo tilẹ̀ ní ìmọ̀?”
12Ẹ wò ó! Ayé àwọn eniyan burúkú nìwọ̀nyí;
ara dẹ̀ wọ́n nígbà gbogbo, ọrọ̀ wọn sì ń pọ̀ sí i.
13Lásán ni gbogbo aáyan mi láti rí i pé ọkàn mi mọ́,
tí mo sì yọwọ́-yọsẹ̀ ninu ibi.
14Nítorí pé tọ̀sán-tòru ni mò ń rí ìyọnu;
láràárọ̀ ni à ń jẹ mí níyà.
15Bí mo bá ní, “N óo sọ̀rọ̀ báyìí,”
n óo kó àwọn ọmọ rẹ ṣìnà.
16Ṣugbọn nígbà tí mo rò bí nǹkan wọnyi ṣe lè yé mi,
mo rí i pé iṣẹ́ tíí dáni lágara ni.
17Àfi ìgbà tí mo wọ ibi mímọ́ Ọlọrun lọ,
ni mo tó wá rí òye ìgbẹ̀yìn wọn.
18Nítòótọ́ ibi tí ń yọ̀ ni ó gbé wọn lé,
ó sì mú kí wọn ṣubú sinu ìparun.
19Wò ó bí wọn ṣe parun lọ́gán,
tí ìpayà sì gbá wọn lọ patapata.
20Wọ́n dàbí àlá tíí pòórá nígbà tí eniyan bá ta jí.
OLUWA, nígbà tí o bá jí gìrì, wọn óo pòórá.
21Nígbà tí ọkàn mí bàjẹ́,
tí ọ̀rọ̀ náà gbóná lára mi,
22mo hùwà òmùgọ̀, n kò sì lóye,
mo sì dàbí ẹranko lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ.
23Sibẹsibẹ nígbà gbogbo ni mo wà lọ́dọ̀ rẹ;
o sì di ọwọ́ ọ̀tún mi mú.
24Ò ń fi ìmọ̀ràn rẹ tọ́ mi sọ́nà;
lẹ́yìn náà, o óo sì gbà mí sinu ògo.
25Ta ni mo ní lọ́run lẹ́yìn rẹ?
Kò sì sí ohun kan tí ó wù mí láyé yìí bíkòṣe ìwọ.
26Àárẹ̀ lè mú ara ati ẹ̀mí mi,
ṣugbọn Ọlọrun ni agbára ẹ̀mí mi,
ati ìpín mi títí lae.
27Ó dájú pé àwọn tí ó jìnnà sí ọ yóo ṣègbé,
o óo sì pa àwọn tí ó bá ṣe alaiṣootọ sí ọ run.
28Ní tèmi o, ó dára láti súnmọ́ Ọlọrun;
mo ti fi ìwọ OLUWA Ọlọrun ṣe ààbò mi,
kí n lè máa ròyìn gbogbo iṣẹ́ rẹ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 73: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀