ORIN DAFIDI 61

61
Adura Ààbò
1Gbọ́ igbe mi, Ọlọrun,
fetí sí adura mi.
2Láti ọ̀nà jíjìn réré ni mo ti ké pè ọ́,
nígbà tí àárẹ̀ mú mi.
Tọ́ mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ,
3nítorí ìwọ ni ààbò mi,
ìwọ ni ilé ìṣọ́ tí ó lágbára
láti dáàbò bò mí lọ́wọ́ ọ̀tá.
4Jẹ́ kí n máa gbé inú àgọ́ rẹ títí lae,
kí n lè máa wà láìléwu lábẹ́ ààbò ìyẹ́ rẹ.
5Nítorí ìwọ, Ọlọrun, ti gbọ́ ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́;
o ti fún mi ní ogún tí o pèsè fún àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ.
6Jẹ́ kí ẹ̀mí ọba ó gùn;
kí ó pẹ́ láyé kánrinkése.
7Kí ó máa gúnwà níwájú Ọlọrun títí lae;
máa fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, ati òtítọ́ rẹ ṣọ́ ọ.
8Bẹ́ẹ̀ ni n óo máa kọ orin ìyìn orúkọ rẹ títí lae,
nígbà tí mo bá ń san ẹ̀jẹ́ mi lojoojumọ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 61: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀