ORIN DAFIDI 62

62
Ọlọrun ni Ààbò Wa
1Ọlọrun nìkan ni mo fi sùúrù gbẹ́kẹ̀lé;
ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìgbàlà mi ti wá.
2Òun nìkan ni àpáta ati olùgbàlà mi,
òun ni odi mi, a kì yóo tì mí kúrò.
3Yóo ti pẹ́ tó, tí gbogbo yín yóo dojú kọ ẹnìkan ṣoṣo, láti pa,
ẹni tí kò lágbára ju ògiri tí ó ti fẹ́ wó lọ, tabi ọgbà tí ó fẹ́ ya?
4Wọ́n fẹ́ ré e bọ́ láti ipò ọlá rẹ̀.
Inú wọn a máa dùn sí irọ́.
Wọ́n ń fi ẹnu wọn súre,
ṣugbọn ní ọkàn wọn, èpè ni wọ́n ń ṣẹ́.
5Ọlọrun nìkan ni mo fi sùúrù gbẹ́kẹ̀lé,
nítorí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí mi ti wá.
6Òun nìkan ni àpáta ati olùgbàlà mi,
òun ni odi mi, a kì yóo tì mí kúrò.
7Ọwọ́ Ọlọrun ni ìgbàlà ati ògo mi wà;
òun ni àpáta agbára mi ati ààbò mi.
8Ẹ gbẹ́kẹ̀lé e nígbà gbogbo, ẹ̀yin eniyan;
ẹ tú ẹ̀dùn ọkàn yín palẹ̀ níwájú rẹ̀;
OLUWA ni ààbò wa.
9Afẹ́fẹ́ lásán ni àwọn mẹ̀kúnnù;
ìtànjẹ patapata sì ni àwọn ọlọ́lá;
bí a bá gbé wọn lé ìwọ̀n, wọn kò lè tẹ̀wọ̀n;
àpapọ̀ wọn fúyẹ́ ju afẹ́fẹ́ lọ.
10Má gbẹ́kẹ̀lé ìlọ́ni-lọ́wọ́-gbà,
má sì fi olè jíjà yangàn;
bí ọrọ̀ bá ń pọ̀ sí i, má gbé ọkàn rẹ lé e.
11Ọlọrun ti sọ̀rọ̀ níbìkan,
mo sì ti gbọ́ ọ bí ìgbà mélòó kan pé,
Ọlọrun ló ni agbára;
12ati pé, tìrẹ, OLUWA ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.
Ò máa san ẹ̀san fún eniyan
gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ bá ti rí.#Job 34:11; Jer 17:10; Mat 16:27; Ifi 2:23

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 62: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀