ORIN DAFIDI 60

60
Adura fún Ìgbàlà#2Sam 8:13; 1Kron 18:12
1Ọlọrun, o ti kọ̀ wá sílẹ̀,
o ti wó odi wa;
o ti bínú, dákun, mú wa bọ̀ sípò.
2O ti mú kí ilẹ̀ mì tìtì;
o ti mú kí ó yanu;
dí gbogbo ibi tí ilẹ̀ ti ya, nítorí pé ó ń mì.
3O ti jẹ́ kí àwọn eniyan rẹ ní ọpọlọpọ ìnira,
o ti fún wa ní ọtí mu tóbẹ́ẹ̀ tí à ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n.
4O ti ta àsíá ogun fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,
kí wọ́n baà lè rí ààbò lọ́wọ́ ọfà ọ̀tá.
5Kí á lè gba àyànfẹ́ rẹ là,
fi ọwọ́ agbára rẹ ṣẹgun fún wa,
kí o sì dá wa lóhùn.
6Ọlọrun ti sọ̀rọ̀ ninu ilé mímọ́ rẹ̀,
ó ní, “Tayọ̀tayọ̀ ni n óo fi pín Ṣekemu,
n óo sì pín àfonífojì Sukotu.#60:6 Bákan náà ni 60:6-12 ati 108:7-13 .
7Tèmi ni Gileadi, tèmi sì ni Manase;
Efuraimu ni àkẹtẹ̀ àṣíborí mi,
Juda sì ni ọ̀pá àṣẹ mi.
8Moabu ni ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi;
lórí Edomu ni n óo bọ́ bàtà mi lé;
n óo sì hó ìhó ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí Filistia.”
9Ta ni yóo mú mi wọ inú ìlú olódi náà?
Ta ni yóo mú mi lọ sí Edomu?
10Ọlọrun, o kò ha ti kọ̀ wá sílẹ̀?
Ọlọrun, o ò bá àwọn ọmọ ogun wa jáde lọ sójú ogun mọ́.
11Ràn wá lọ́wọ́, bá wa gbógun ti àwọn ọ̀tá wa,
nítorí pé asán ni ìrànlọ́wọ́ eniyan.
12Pẹlu àtìlẹ́yìn Ọlọrun a óo ṣe akin,
nítorí òun ni yóo tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 60: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀