ORIN DAFIDI 58:1-11

ORIN DAFIDI 58:1-11 YCE

Ǹjẹ́ ìpinnu tí ẹ̀ ń ṣe tọ̀nà, ẹ̀yin aláṣẹ? Ǹjẹ́ ẹ̀ ń ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan ní ọ̀nà ẹ̀tọ́? Rárá o! Ibi ni ẹ̀ ń fi ọkàn yín rò, iṣẹ́ burúkú ni ẹ sì ń fi ọwọ́ yín ṣe láyé. Láti inú oyún ni àwọn eniyan burúkú ti ṣìnà, láti ọjọ́ tí a ti bí wọn ni wọ́n tí ń ṣìṣe, tí wọn ń purọ́. Wọ́n ní oró bí oró ejò, wọ́n dití bíi paramọ́lẹ̀ tí ó di etí ara rẹ̀, kí ó má baà gbọ́ ohùn afunfèrè, tabi ìpè adáhunṣe. Kán eyín mọ́ wọn lẹ́nu, Ọlọrun; OLUWA! Yọ ọ̀gàn àwọn ẹgbọ̀rọ̀ kinniun. Jẹ́ kí wọ́n rá, kí wọn ṣàn lọ bí omi; kí á tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bíi koríko, kí wọn sì rọ. Kí wọn dàbí ìgbín tí a tẹ̀ ní àtẹ̀rẹ́, tí ó domi, ati bí òkúmọ tí kò fojú kan ìmọ́lẹ̀ ayé rí. Lójijì, a ó ké eniyan burúkú lulẹ̀; ìjì ibinu Ọlọrun yóo sì gbá wọn lọ. Olódodo yóo yọ̀ nígbà tí ẹ̀san bá ń ké, yóo fi ẹsẹ̀ wọ́ àgbàrá ẹ̀jẹ̀ àwọn eniyan burúkú. Àwọn eniyan yóo wí nígbà náà pé, “Nítòótọ́, èrè ń bẹ fún olódodo; nítòótọ́, Ọlọrun ń bẹ tí ń ṣe ìdájọ́ ayé.”