ẸNYIN ha nsọ ododo nitõtọ, ẹnyin ijọ enia? ẹnyin ha nṣe idajọ ti o ṣe titọ, ẹnyin ọmọ enia? Nitõtọ, ẹnyin nṣiṣẹ buburu li aiya; ẹnyin nwọ̀n ìwa-agbara ọwọ nyin li aiye. Lati inu iya wọn wá li awọn enia buburu ti ṣe iyapa: nwọn ti ṣina lojukanna ti a ti bi wọn, nwọn a ma ṣeke. Oró wọn dabi oró ejò: nwọn dabi aditi ejò pamọlẹ ti o di ara rẹ̀ li eti; Ti kò fẹ igbọ́ ohùn awọn atuniloju, bi o ti wù ki o ma fi ọgbọ́n ṣe ituju to. Ká wọn li ehin, Ọlọrun, li ẹnu wọn: ká ọ̀gan awọn ọmọ kiniun nì, Oluwa. Ki nwọn ki o yọ́ danu bi omi ti nṣàn nigbagbogbo: nigbati o ba fa ọrun lati tafà rẹ̀, ki nwọn ki o dabi ẹnipe a ke wọn ni ijanja. Bi igbín ti a tẹ̀ rẹ́ ti o si ṣegbe: bi iṣẹnu obinrin, bẹ̃ni ki nwọn ki o má ṣe ri õrùn. Ki ikoko nyin ki o to mọ̀ igbona ẹgún, iba tutu iba ma jo, yio fi iji gbá wọn lọ. Olododo yio yọ̀ nigbati o ba ri ẹsan na: yio si wẹ̀ ẹsẹ rẹ̀ ninu ẹ̀jẹ awọn enia buburu. Bẹ̃li enia o si wipe, Lõtọ, ère mbẹ fun olododo: lõtọ, on li Ọlọrun ti o nṣe idajọ ni aiye.
Kà O. Daf 58
Feti si O. Daf 58
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 58:1-11
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò