ORIN DAFIDI 53
53
Èrè Òmùgọ̀
(Orin 14)
1Òmùgọ̀ sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé,
“Kò sí Ọlọrun.”
Wọ́n bàjẹ́, ohun ìríra ni wọ́n ń ṣe,
kò sì sí ẹnìkan ninu wọn tí ń ṣe rere.
2Ọlọrun bojú wo àwọn ọmọ eniyan láti ọ̀run wá,
ó ń wò ó bí àwọn kan bá wà tí òye yé,
àní, bí àwọn kan bá wà tí ń wá Ọlọrun.
3Gbogbo wọn ni ó ti yapa;
tí wọn sì ti bàjẹ́,
kò sí ẹnìkan tí ń ṣe rere,
kò sí, bó tilẹ̀ jẹ́ ẹnìkan ṣoṣo.#Rom 3:10-12
4Ṣé gbogbo àwọn aṣebi kò gbọ́n ni?
Àwọn tí ń jẹ eniyan mi bí ẹni jẹun,
àní àwọn tí kì í ké pe Ọlọrun.
5Ẹ wò wọ́n, bí wọ́n ṣe wà ninu ẹ̀rù ńlá,
ẹ̀rù tí kò tíì sí irú rẹ̀ rí!
Nítorí Ọlọrun yóo fọ́n egungun àwọn ọ̀tá rẹ̀ ká;
ojú óo tì wọ́n, nítorí Ọlọrun ti kọ̀ wọ́n.
6Ìbá ti dára tó, kí ìgbàlà Israẹli ti Sioni wá!
Nígbà tí Ọlọrun bá dá ire àwọn eniyan rẹ̀ pada,
Jakọbu yóo yọ̀, inú Israẹli yóo sì dùn.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ORIN DAFIDI 53: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010