ORIN DAFIDI 54

54
Adura Ààbò#1Sam 23:19; 26:1
1Fi agbára orúkọ rẹ gbà mí, Ọlọrun,
fi ipá rẹ dá mi láre.
2Gbọ́ adura mi, Ọlọrun;
tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.
3Nítorí pé àwọn agbéraga dìde sí mi,
àwọn ìkà, aláìláàánú sì ń lépa ẹ̀mí mi;
wọn kò bìkítà fún Ọlọrun.
4Ṣugbọn Ọlọrun ni olùrànlọ́wọ́ mi,
OLUWA ni ó gbé ẹ̀mí mi ró.
5Yóo san ẹ̀san ibi fún àwọn ọ̀tá mi;
OLUWA, nítorí òtítọ́ rẹ, pa wọ́n run.
6N óo rú ẹbọ ọrẹ àtinúwá sí ọ,
n óo máa yin orúkọ rẹ, OLUWA,
nítorí pé ó dára bẹ́ẹ̀.
7O ti yọ mí ninu gbogbo ìṣòro mi,
mo sì ti fi ojú mi rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 54: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀