ORIN DAFIDI 52

52
Ìdájọ́ ati Oore Ọ̀fẹ́ Ọlọrun#1Sam 22:9-10
1Ìwọ alágbára, kí ló dé tí o fi ń fọ́nnu,
kí ló dé tí ò ń fọ́nnu tọ̀sán-tòru?
Ẹni ìtìjú ni ọ́ lójú Ọlọrun.
2Ò ń pète ìparun;
ẹnu rẹ dàbí abẹ tí ó mú, ìwọ alárèékérekè.
3O fẹ́ràn ibi ju ire lọ,
o sì fẹ́ràn irọ́ ju òtítọ́ lọ.
4O fẹ́ràn gbogbo ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́,
Ìwọ ẹlẹ́tàn!
5Nítòótọ́ Ọlọrun óo bá ọ kanlẹ̀,
yóo gbá ọ mú, yóo sì fà ọ́ já kúrò ninu ilé rẹ;
yóo fà ọ́ tu kúrò lórí ilẹ̀ alààyè.
6Nígbà tí àwọn olódodo bá rí i, ẹ̀rù óo bà wọ́n,
wọn óo fi rẹ́rìn-ín, wọn óo sì wí pé,
7“Wo ẹni tí ó kọ̀, tí kò fi Ọlọrun ṣe ààbò rẹ̀,
ṣugbọn ó gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ rẹ̀ tí ó pọ̀,
ati jamba tí ó ń ta fún ẹlòmíràn.”
8Ṣugbọn èmi dàbí igi olifi tútù
tí ń dàgbà ninu ilé OLUWA,
mo gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọrun tí kì í yẹ̀, lae ati laelae.
9N óo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ títí lae,
nítorí ohun tí o ṣe,
n óo máa kéde orúkọ rẹ níwájú àwọn olùfọkànsìn rẹ,
nítorí pé ó dára bẹ́ẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 52: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀