ORIN DAFIDI 51

51
Adura Ìdáríjì#2Sam 12:1-15
1Ṣàánú mi, Ọlọrun, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀;
nítorí ọ̀pọ̀ àánú rẹ pa ẹ̀ṣẹ̀ mi rẹ́.
2Wẹ̀ mí mọ́ kúrò ninu àìdára mi,
kí o sì wẹ̀ mí kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ mi!
3Nítorí mo mọ ibi tí mo ti ṣẹ̀,
nígbà gbogbo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi sì wà níwájú mi.
4Ìwọ nìkan, àní, ìwọ nìkan ṣoṣo ni mo ṣẹ̀,
tí mo ṣe ohun tí ó burú lójú rẹ,
kí ẹjọ́ rẹ lè tọ́ nígbà tí o bá ń dájọ́,
kí ọkàn rẹ lè mọ́ nígbà tí o bá ń ṣe ìdájọ́.
5Dájúdájú, ninu àìdára ni a bí mi,
ninu ẹ̀ṣẹ̀ ni ìyá mi sì lóyún mi.#Rom 3:4
6O fẹ́ràn òtítọ́ inú;
nítorí náà, kọ́ mi lọ́gbọ́n ní kọ́lọ́fín ọkàn mi.
7Fi ewé hisopu fọ̀ mí, n óo sì mọ́;
wẹ̀ mí, n óo sì funfun ju ẹ̀gbọ̀n òwú lọ.
8Fún mi ní ayọ̀ ati inú dídùn,
kí gbogbo egungun mi tí ó ti rún lè máa yọ̀.
9Mójú kúrò lára ẹ̀ṣẹ̀ mi,
kí o sì pa gbogbo àìdára mi rẹ́.
10Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọrun,
kí o sì fi ẹ̀mí ọ̀tun ati ẹ̀mí ìṣòótọ́ sí mi lọ́kàn.
11Má ta mí nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ,
má sì gba Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ lọ́wọ́ mi.
12Dá ayọ̀ ìgbàlà rẹ pada fún mi,
kí o sì fi ẹ̀mí àtiṣe ìfẹ́ rẹ gbé mi ró.
13Nígbà náà ni n óo máa kọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ọ̀nà rẹ,
àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóo sì máa yipada sí ọ.
14Gbà mí lọ́wọ́ ẹ̀bi ìpànìyàn, Ọlọrun,
ìwọ Ọlọrun, Olùgbàlà mi,
n óo sì máa fi orin kéde iṣẹ́ rere rẹ.
15OLUWA, là mí ní ohùn,
n óo sì máa ròyìn iṣẹ́ ńlá rẹ.
16Bí ó bá jẹ́ pé o fẹ́ ẹbọ ni, ǹ bá mú wá fún ọ;
ṣugbọn o ò tilẹ̀ fẹ́ ẹbọ sísun.
17Ẹbọ tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ ìwọ Ọlọrun ni ẹ̀mí ìròbìnújẹ́,
ọkàn ìròbìnújẹ́ ati ìrònúpìwàdà ni ìwọ kì yóo gàn.
18Jẹ́ kí ó dára fún Sioni ninu ìdùnnú rẹ;
tún odi Jerusalẹmu mọ.
19Nígbà náà ni inú rẹ yóo dùn sí ẹbọ tí ó tọ́,
ẹbọ sísun, ati ẹbọ tí a sun lódidi;
nígbà náà ni a óo fi akọ mààlúù rúbọ lórí pẹpẹ rẹ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 51: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀