ORIN DAFIDI 41

41
Adura Ẹni tí ń Ṣàìsàn
1Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ń ro ti àwọn aláìní:
OLUWA yóo gbà á ní ọjọ́ ìpọ́njú.
2OLUWA yóo máa ṣọ́ ọ, yóo sì dá a sí.
Yóo ní ayọ̀ ní ilẹ̀ náà;
OLUWA kò ní fi í lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́.
3Nígbà tí ó bá wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn,
OLUWA yóo fún un lókun;
ní àkókò àìlera OLUWA yóo wo gbogbo àrùn rẹ̀ sàn.
4Mo ní, “OLUWA, ṣàánú mi kí o sì wò mí sàn;
mo ti ṣẹ̀ ọ́.”
5Àwọn ọ̀tá mi ń ro ibi sí mi, wọ́n ń wí pé,
“Nígbà wo ni yóo kú, tí orúkọ rẹ̀ yóo parẹ́?”
6Tí ọ̀kan bá wá bẹ̀ mí wò,
ọ̀rọ̀ tí kò lórí, tí kò nídìí
ni yóo máa sọ;
bẹ́ẹ̀ ni ninu ọkàn rẹ̀, èrò ibi ni yóo máa gbà.
Nígbà tí ó bá jáde,
yóo máa rò mí kiri.
7Gbogbo àwọn tí ó kórìíra mi
jọ ń sọ̀rọ̀ wújẹ́wújẹ́ nípa mi;
ohun tó burú jùlọ ni wọ́n ń rò sí mi.
8Wọ́n ń wí pé, “Àìsàn burúkú ti gbé e dálẹ̀;
kò ní dìde mọ́ níbi tí ó dùbúlẹ̀ sí.”
9Àní ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi tí mo gbẹ́kẹ̀lé,
tí ó ń jẹun nílé mi,
ó ti kẹ̀yìn sí mí.#Mat 26:23; Mak 14:18; Luk 22:21; Joh 13:18
10Ṣugbọn, OLUWA, ṣàánú mi;
gbé mi dìde, kí n lè san ẹ̀san fún un.
11Kí n lè mọ̀ pé o fẹ́ràn mi,
nígbà tí ọ̀tá kò bá borí mi.
12O ti gbé mi ró nítorí ìwà pípé mi,
o sì fi ẹsẹ̀ mi múlẹ̀ níwájú rẹ títí lae.
13Ìyìn ni fún OLUWA, Ọlọrun Israẹli,
lae ati laelae.
Amin! Amin!#O. Daf 106:48
ÌWÉ ORIN KEJI
(Orin Dafidi 42–72)

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 41: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀