ORIN DAFIDI 33:1-11

ORIN DAFIDI 33:1-11 YCE

Ẹ máa yọ̀ ninu OLUWA, ẹ̀yin olódodo! Yíyin OLUWA ni ó yẹ ẹ̀yin olóòótọ́. Ẹ fi gòjé yin OLUWA, ẹ fi hapu olókùn mẹ́wàá kọ orin sí i. Ẹ kọ orin titun sí i, ẹ fi ohun èlò ìkọrin olókùn dárà, kí ẹ sì hó ìhó ayọ̀. Nítorí ọ̀rọ̀ OLUWA dúró ṣinṣin; òtítọ́ sì ni ó fi ń ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ̀. OLUWA fẹ́ràn òdodo ati ẹ̀tọ́; ayé kún fún ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀. Ọ̀rọ̀ ni OLUWA fi dá ojú ọ̀run, èémí ẹnu rẹ̀ ni ó sì fi dá oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀. Ó wọ́ gbogbo omi òkun jọ bí òkìtì; ó pa gbogbo omi inú àwọn ibú pọ̀ bí ẹni pé ó rọ ọ́ sinu àgbá ńlá. Kí gbogbo ayé bẹ̀rù OLUWA, kí gbogbo aráyé dúró níwájú rẹ̀ pẹlu ọ̀wọ̀ ati ìbẹ̀rù! Nítorí pé OLUWA sọ̀rọ̀, ayé wà; ó pàṣẹ, ayé sì dúró. OLUWA sọ ìmọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè di asán; ó sì mú kí ètò àwọn eniyan já sófo. Ètò OLUWA wà títí lae, èrò ọkàn rẹ̀ sì wà láti ìran dé ìran.