ORIN DAFIDI 33

33
Orin Ìyìn
1Ẹ máa yọ̀ ninu OLUWA, ẹ̀yin olódodo!
Yíyin OLUWA ni ó yẹ ẹ̀yin olóòótọ́.
2Ẹ fi gòjé yin OLUWA,
ẹ fi hapu olókùn mẹ́wàá kọ orin sí i.
3Ẹ kọ orin titun sí i,
ẹ fi ohun èlò ìkọrin olókùn dárà,
kí ẹ sì hó ìhó ayọ̀.
4Nítorí ọ̀rọ̀ OLUWA dúró ṣinṣin;
òtítọ́ sì ni ó fi ń ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.
5OLUWA fẹ́ràn òdodo ati ẹ̀tọ́;
ayé kún fún ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.
6Ọ̀rọ̀ ni OLUWA fi dá ojú ọ̀run,
èémí ẹnu rẹ̀ ni ó sì fi dá oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀.
7Ó wọ́ gbogbo omi òkun jọ bí òkìtì;
ó pa gbogbo omi inú àwọn ibú pọ̀ bí ẹni pé ó rọ ọ́ sinu àgbá ńlá.
8Kí gbogbo ayé bẹ̀rù OLUWA,
kí gbogbo aráyé dúró níwájú rẹ̀ pẹlu ọ̀wọ̀ ati ìbẹ̀rù!
9Nítorí pé OLUWA sọ̀rọ̀, ayé wà;
ó pàṣẹ, ayé sì dúró.
10OLUWA sọ ìmọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè di asán;
ó sì mú kí ètò àwọn eniyan já sófo.
11Ètò OLUWA wà títí lae,
èrò ọkàn rẹ̀ sì wà láti ìran dé ìran.
12Ayọ̀ ń bẹ fún orílẹ̀-èdè tí OLUWA jẹ́ Ọlọrun wọn,
àní àwọn eniyan tí ó yàn gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀!
13OLUWA bojúwo ilẹ̀ láti ọ̀run,
ó rí gbogbo eniyan;
14láti orí ìtẹ́ rẹ̀ tí ó gúnwà sí,
ó wo gbogbo aráyé.
15Òun ni ó dá ọkàn gbogbo wọn,
tí ó sì ń mójútó gbogbo ìṣe wọn.
16Kì í ṣe pípọ̀ tí àwọn ọmọ ogun pọ̀ ní ń gba ọba là;
kì í sì í ṣe ọ̀pọ̀ agbára níí gba jagunjagun là.
17Asán ni igbẹkẹle agbára ẹṣin ogun;
kìí ṣe agbára tí ẹṣin ní, ló lè gbani là.#Jud 9:7; 1 Makab 3:19
18Wò ó! OLUWA ń ṣọ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
àní àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,
19kí ó lè gba ọkàn wọn lọ́wọ́ ikú,
kí ó sì mú wọn wà láàyè lákòókò ìyàn.
20Ọkàn wa ní ìrètí lọ́dọ̀ OLUWA;
òun ni olùrànlọ́wọ́ ati ààbò wa.
21A láyọ̀ ninu rẹ̀,
nítorí pé a gbẹ́kẹ̀lé orúkọ mímọ́ rẹ̀.
22OLUWA, jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ wà lórí wa
bí a ti gbẹ́kẹ̀lé ọ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 33: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀