ORIN DAFIDI 34

34
Ẹ yin Ọlọrun nítorí Oore Rẹ̀#1Sam 21:13-15
1N óo máa yin OLUWA ní gbogbo ìgbà;
ìyìn rẹ̀ yóo máa wà ní ẹnu mi nígbà gbogbo.
2OLUWA ni èmi óo máa fi yangàn;
kí inú àwọn olùpọ́njú máa dùn nígbà tí wọ́n bá gbọ́.
3Ẹ bá mi gbé OLUWA ga,
ẹ jẹ́ kí á jùmọ̀ gbé orúkọ rẹ̀ lékè!
4Mo ké pe OLUWA, ó sì dá mi lóhùn,
ó sì gbà mí lọ́wọ́ gbogbo ohun tí ń bà mí lẹ́rù.
5Wọ́n gbójú sókè sí OLUWA, wọ́n láyọ̀;#34:5 tabi “àwọn olùpọ́njú wo ojú OLUWA”
ojú kò sì tì wọ́n.
6Olùpọ́njú ké pe OLUWA, OLUWA gbọ́ ohùn rẹ̀,
ó sì gbà á ninu gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.
7Angẹli OLUWA yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká,
a sì máa gbà wọ́n.
8Tọ́ ọ wò, kí o sì rí i pé rere ni OLUWA!
Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá sá di í!
9Ẹ bẹ̀rù OLUWA, ẹ̀yin eniyan mímọ́ rẹ̀,
nítorí pé kò sí àìní fún àwọn tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀!
10Àwọn ọmọ kinniun a máa ṣe aláìní,
ebi a sì máa pa wọ́n;
ṣugbọn àwọn tí wọ́n bá ń wá OLUWA
kò ní ṣe aláìní ohun rere kankan.#1 Pet 2:3
11Ẹ wá, ẹ̀yin ọmọ, ẹ tẹ́tí sí mi,
n óo kọ yín ní ìbẹ̀rù OLUWA.
12Ta ni ń fẹ́ ìyè ninu yín,
tí ń fẹ́ ẹ̀mí gígùn,
tí ó fẹ́ pẹ́ láyé?
13Ẹ ṣọ́ ẹnu yín, ẹ má sọ̀rọ̀ burúkú,
ẹ má sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ti ẹnu yín jáde.
14Ẹ yàgò fún ibi, rere ni kí ẹ máa ṣe;
ẹ máa wá alaafia, kí ẹ sì máa lépa rẹ̀.
15OLUWA ń ṣọ́ àwọn olódodo,
Ó sì ń dẹ etí sí igbe wọn.
16OLUWA fojú sí àwọn aṣebi lára,
láti pa wọ́n rẹ́, kí á má sì ṣe ranti wọn mọ́ lórí ilẹ̀ ayé.
17Nígbà tí olódodo bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́, OLUWA a máa gbọ́,
a sì máa gbà wọ́n kúrò ninu gbogbo ìyọnu wọn.
18OLUWA wà nítòsí àwọn tí ọkàn wọn bàjẹ́,
a sì máa gba àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn là.
19Ìpọ́njú olódodo a máa pọ̀;
ṣugbọn OLUWA a máa kó o yọ ninu gbogbo wọn.
20A máa pa gbogbo egungun rẹ̀ mọ́;
kì í jẹ́ kí ọ̀kankan fọ́ ninu wọn.
21Ibi ni yóo pa eniyan burúkú;
a óo sì dá àwọn tí ó kórìíra olódodo lẹ́bi.#1 Pet 3:10-12 #Joh 19:36
22OLUWA ra ẹ̀mí àwọn iranṣẹ rẹ̀ pada;
ẹnikẹ́ni tí ó bá sá di í kò ní jẹ̀bi.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 34: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa