O. Daf 33:1-11
O. Daf 33:1-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
ẸMA yọ̀ niti Oluwa, ẹnyin olododo: nitoriti iyìn yẹ fun ẹni-diduro-ṣinṣin. Ẹ ma fi duru yìn Oluwa: ẹ ma fi ohun-elo olokùn mẹwa kọrin si i. Ẹ kọ orin titun si i: ẹ ma fi ọgbọngbọn lù ohun ọnà orin pẹlu ariwo. Nitori ti ọ̀rọ Oluwa tọ́: ati gbogbo iṣẹ rẹ̀ li a nṣe ninu otitọ. O fẹ otitọ ati idajọ: ilẹ aiye kún fun ãnu Oluwa. Nipa ọ̀rọ Oluwa li a da awọn ọrun, ati gbogbo ogun wọn nipa ẽmí ẹnu rẹ̀. O gbá awọn omi okun jọ bi ẹnipe òkiti kan: o tò ibu jọ ni ile iṣura. Ki gbogbo aiye ki o bẹ̀ru Oluwa: ki gbogbo araiye ki o ma wà ninu ẹ̀ru rẹ̀. Nitori ti o sọ̀rọ, o si ti ṣẹ; o paṣẹ, o si duro ṣinṣin. Oluwa mu ìmọ awọn orilẹ-ède di asan: o mu arekereke awọn enia ṣaki. Imọ Oluwa duro lailai, ìro inu rẹ̀ lati irandiran.
O. Daf 33:1-11 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ máa yọ̀ ninu OLUWA, ẹ̀yin olódodo! Yíyin OLUWA ni ó yẹ ẹ̀yin olóòótọ́. Ẹ fi gòjé yin OLUWA, ẹ fi hapu olókùn mẹ́wàá kọ orin sí i. Ẹ kọ orin titun sí i, ẹ fi ohun èlò ìkọrin olókùn dárà, kí ẹ sì hó ìhó ayọ̀. Nítorí ọ̀rọ̀ OLUWA dúró ṣinṣin; òtítọ́ sì ni ó fi ń ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ̀. OLUWA fẹ́ràn òdodo ati ẹ̀tọ́; ayé kún fún ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀. Ọ̀rọ̀ ni OLUWA fi dá ojú ọ̀run, èémí ẹnu rẹ̀ ni ó sì fi dá oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀. Ó wọ́ gbogbo omi òkun jọ bí òkìtì; ó pa gbogbo omi inú àwọn ibú pọ̀ bí ẹni pé ó rọ ọ́ sinu àgbá ńlá. Kí gbogbo ayé bẹ̀rù OLUWA, kí gbogbo aráyé dúró níwájú rẹ̀ pẹlu ọ̀wọ̀ ati ìbẹ̀rù! Nítorí pé OLUWA sọ̀rọ̀, ayé wà; ó pàṣẹ, ayé sì dúró. OLUWA sọ ìmọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè di asán; ó sì mú kí ètò àwọn eniyan já sófo. Ètò OLUWA wà títí lae, èrò ọkàn rẹ̀ sì wà láti ìran dé ìran.
O. Daf 33:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ yọ̀ nínú OLúWA, ẹ̀yin olódodo ìyìn si yẹ fún ẹni dídúró ṣinṣin. Ẹ yin OLúWA pẹ̀lú dùùrù; ẹ máa fi ohun èlò olókùn mẹ́wàá kọrin sí i. Ẹ kọ orin tuntun sí i; ẹ máa fi ọgbọọgbọ́n lu ohun èlò orin sí i, pẹ̀lú ariwo. Nítorí pé ọ̀rọ̀ OLúWA dúró ṣinṣin, gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ni à ń ṣe nínú òtítọ́. Ó fẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́; ilé ayé kún fún ìdúró ṣinṣin àti àánú OLúWA. Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ OLúWA ni a ṣe dá àwọn ọ̀run, àti gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ogun wọn nípa ìmísí ẹnu rẹ̀. Ó kó àwọn omi Òkun jọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó wà nínú ìgò; ó sì fi ibú ṣe ilé ìṣúra gbogbo. Jẹ́ kí gbogbo ayé kí ó bẹ̀rù OLúWA: jẹ́ kí gbogbo àwọn olùgbé ayé kí ó wà nínú ìbẹ̀rù rẹ̀. Nítorí tí ó sọ̀rọ̀, ó sì ti rí bẹ́ẹ̀; ó pàṣẹ ó sì dúró ṣinṣin. OLúWA ti mú ìmọ̀ràn àwọn orílẹ̀-èdè wá sí asán; ó sì mú àrékérekè àwọn ènìyàn di ṣíṣákì í. Ìgbìmọ̀ OLúWA dúró títí ayérayé, àní ìrò inú rẹ̀ láti ìrandíran ni.