Saamu 33:1-11

Saamu 33:1-11 YCB

Ẹ yọ̀ nínú OLúWA, ẹ̀yin olódodo ìyìn si yẹ fún ẹni dídúró ṣinṣin. Ẹ yin OLúWA pẹ̀lú dùùrù; ẹ máa fi ohun èlò olókùn mẹ́wàá kọrin sí i. Ẹ kọ orin tuntun sí i; ẹ máa fi ọgbọọgbọ́n lu ohun èlò orin sí i, pẹ̀lú ariwo. Nítorí pé ọ̀rọ̀ OLúWA dúró ṣinṣin, gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ni à ń ṣe nínú òtítọ́. Ó fẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́; ilé ayé kún fún ìdúró ṣinṣin àti àánú OLúWA. Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ OLúWA ni a ṣe dá àwọn ọ̀run, àti gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ogun wọn nípa ìmísí ẹnu rẹ̀. Ó kó àwọn omi Òkun jọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó wà nínú ìgò; ó sì fi ibú ṣe ilé ìṣúra gbogbo. Jẹ́ kí gbogbo ayé kí ó bẹ̀rù OLúWA: jẹ́ kí gbogbo àwọn olùgbé ayé kí ó wà nínú ìbẹ̀rù rẹ̀. Nítorí tí ó sọ̀rọ̀, ó sì ti rí bẹ́ẹ̀; ó pàṣẹ ó sì dúró ṣinṣin. OLúWA ti mú ìmọ̀ràn àwọn orílẹ̀-èdè wá sí asán; ó sì mú àrékérekè àwọn ènìyàn di ṣíṣákì í. Ìgbìmọ̀ OLúWA dúró títí ayérayé, àní ìrò inú rẹ̀ láti ìrandíran ni.