ORIN DAFIDI 19:1-14

ORIN DAFIDI 19:1-14 YCE

Ojú ọ̀run ń sọ̀rọ̀ ògo Ọlọrun, òfuurufú sì ń kéde iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Ọjọ́ dé ọjọ́ ń sọ ọ́ ní àsọgbà òru dé òru sì ń fi ìmọ̀ rẹ̀ hàn. Wọn kò fọ èdè kankan, wọn kò sì sọ ọ̀rọ̀; bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọ́ ohùn wọn; sibẹ ìró wọn la gbogbo ayé já, ọ̀rọ̀ wọn sì dé òpin ayé. Ó pàgọ́ fún oòrùn lójú ọ̀run, tí ó ń yọ jáde bí ọkọ iyawo tí ń jáde láti inú yàrá rẹ̀, ati bí akọni tí ara ń wá láti fi tayọ̀tayọ̀ sáré ìje. Láti apá kan ojú ọ̀run ni ó ti ń yọ wá, a máa yípo gbogbo ojú ọ̀run dé apá keji; kò sì sí ohun tí ó bọ́ lọ́wọ́ ooru rẹ̀. Òfin OLUWA pé, a máa sọ ọkàn jí; àṣẹ OLUWA dájú, ó ń sọ òpè di ọlọ́gbọ́n. Ìlànà OLUWA tọ́, ó ń mú ọkàn yọ̀, àṣẹ OLUWA péye, a máa lani lójú. Ìbẹ̀rù OLUWA pé, ó wà títí lae, ìdájọ́ OLUWA tọ́, òdodo ni gbogbo wọn. Wọ́n wuni ju wúrà lọ, àní ju ojúlówó wúrà lọ; wọ́n sì dùn ju oyin, àní, wọ́n dùn ju oyin tí ń kán láti inú afárá lọ. Pẹlupẹlu àwọn ni wọ́n ń ki èmi iranṣẹ rẹ, nílọ̀, èrè pupọ sì ń bẹ ninu pípa wọ́n mọ́. Ṣugbọn ta ni lè mọ àṣìṣe ara rẹ̀? Wẹ̀ mí mọ́ ninu àṣìṣe àìmọ̀ mi. Pa èmi iranṣẹ rẹ mọ́ kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀-ọ́n-mọ̀-dá; má jẹ́ kí wọ́n jọba lórí mi. Nígbà náà ni ara mi yóo mọ́, n kò sì ní jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ńlá. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi, ati àṣàrò ọkàn mi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ní ojú rẹ, OLUWA ibi ààbò mi ati olùràpadà mi.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú ORIN DAFIDI 19:1-14