O. Daf 19:1-14

O. Daf 19:1-14 Yoruba Bible (YCE)

Ojú ọ̀run ń sọ̀rọ̀ ògo Ọlọrun, òfuurufú sì ń kéde iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Ọjọ́ dé ọjọ́ ń sọ ọ́ ní àsọgbà òru dé òru sì ń fi ìmọ̀ rẹ̀ hàn. Wọn kò fọ èdè kankan, wọn kò sì sọ ọ̀rọ̀; bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọ́ ohùn wọn; sibẹ ìró wọn la gbogbo ayé já, ọ̀rọ̀ wọn sì dé òpin ayé. Ó pàgọ́ fún oòrùn lójú ọ̀run, tí ó ń yọ jáde bí ọkọ iyawo tí ń jáde láti inú yàrá rẹ̀, ati bí akọni tí ara ń wá láti fi tayọ̀tayọ̀ sáré ìje. Láti apá kan ojú ọ̀run ni ó ti ń yọ wá, a máa yípo gbogbo ojú ọ̀run dé apá keji; kò sì sí ohun tí ó bọ́ lọ́wọ́ ooru rẹ̀. Òfin OLUWA pé, a máa sọ ọkàn jí; àṣẹ OLUWA dájú, ó ń sọ òpè di ọlọ́gbọ́n. Ìlànà OLUWA tọ́, ó ń mú ọkàn yọ̀, àṣẹ OLUWA péye, a máa lani lójú. Ìbẹ̀rù OLUWA pé, ó wà títí lae, ìdájọ́ OLUWA tọ́, òdodo ni gbogbo wọn. Wọ́n wuni ju wúrà lọ, àní ju ojúlówó wúrà lọ; wọ́n sì dùn ju oyin, àní, wọ́n dùn ju oyin tí ń kán láti inú afárá lọ. Pẹlupẹlu àwọn ni wọ́n ń ki èmi iranṣẹ rẹ, nílọ̀, èrè pupọ sì ń bẹ ninu pípa wọ́n mọ́. Ṣugbọn ta ni lè mọ àṣìṣe ara rẹ̀? Wẹ̀ mí mọ́ ninu àṣìṣe àìmọ̀ mi. Pa èmi iranṣẹ rẹ mọ́ kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀-ọ́n-mọ̀-dá; má jẹ́ kí wọ́n jọba lórí mi. Nígbà náà ni ara mi yóo mọ́, n kò sì ní jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ńlá. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi, ati àṣàrò ọkàn mi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ní ojú rẹ, OLUWA ibi ààbò mi ati olùràpadà mi.

O. Daf 19:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Àwọn ọ̀run ń sọ nípa ti ògo Ọlọ́run; Àwọsánmọ̀ ń sọ nípa ti iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Wọ́n ń fọhùn ní ọjọ́ dé ọjọ́; wọ́n ń fi ìmọ̀ hàn ní alẹ́ dé alẹ́. Kò sí ohùn tàbí èdè níbi tí a kò gbé gbọ́ ìró wọn Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo orílẹ̀ ayé, ọ̀rọ̀ wọn títí dé òpin ilẹ̀ ayé. Ó ti kọ́ àgọ́ fún oòrùn nínú àwọn ọ̀run. Tí ó dàbí ọkọ ìyàwó tí ó ń jáde ti yàrá rẹ̀ wá, òun yọ bí alágbára ọkùnrin tí ó ń sáré ìje. Ìjáde lọ rẹ̀ ni láti òpin ọ̀run wá àti àyíká rẹ̀ sì dé ìpínlẹ̀ rẹ̀; kò sì sí ohun tí ó pamọ́ kúrò nínú oore rẹ̀. Pípé ni òfin OLúWA, ó ń yí ọkàn padà. Ẹ̀rí OLúWA dánilójú, ó sọ òpè di ọlọ́gbọ́n. Ìlànà OLúWA tọ̀nà, ó ń fi ayọ̀ fún ọkàn. Àṣẹ OLúWA ni mímọ́, ó ń fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú. Ìbẹ̀rù OLúWA mọ́, ó ń faradà títí láéláé. Ìdájọ́ OLúWA dájú òdodo ni gbogbo wọn. Wọn ṣọ̀wọ́n ju wúrà lọ, ju wúrà tí o dára jùlọ, wọ́n dùn ju oyin lọ, àti ju afárá oyin lọ. Nípa wọn ni a ti ṣí ìránṣẹ́ rẹ̀ létí; nípa pípa wọ́n mọ́, èrè púpọ̀ ń bẹ. Ta ni ó lè mọ àṣìṣe rẹ̀? Dáríjì mí nínú àṣìṣe mi tí ó pamọ́. Wẹ ìránṣẹ́ rẹ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́n-mọ̀-dá; má ṣe jẹ kí wọn kí ó jẹ ọba lórí mi. Nígbà náà ní èmi yóò dúró ṣinṣin, èmi yóò sì ṣe aláìlẹ́bi kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ńlá. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn mi kí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ní ojú rẹ, Ìwọ OLúWA àpáta mi, àti Olùdáǹdè mi.

O. Daf 19:1-14

O. Daf 19:1-14 YBCVO. Daf 19:1-14 YBCV