ORIN DAFIDI 18:19-21

ORIN DAFIDI 18:19-21 YCE

Ó mú mi jáde wá síbi tí ó láàyè, ó yọ mí jáde nítorí tí inú rẹ̀ dùn sí mi. OLUWA ti san án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi, bí ọwọ́ mi ṣe mọ́ ni ó ṣe pín mi lérè. Nítorí tí mo ti pa ọ̀nà OLUWA mọ́, n kò ṣe ibi nípa yíyà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun mi.