O. Daf 18:19-21
O. Daf 18:19-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
O mu mi jade pẹlu sinu ibi nla; o gbà mi nitori inu rẹ̀ dùn si mi. Oluwa san a fun mi gẹgẹ bi ododo mi; gẹgẹ bi mimọ́ ọwọ mi li o san a fun mi. Nitori mo ti nkiye si ọ̀na Oluwa, emi kò fi ìka yà kuro lọdọ Ọlọrun mi.
Pín
Kà O. Daf 18O. Daf 18:19-21 Yoruba Bible (YCE)
Ó mú mi jáde wá síbi tí ó láàyè, ó yọ mí jáde nítorí tí inú rẹ̀ dùn sí mi. OLUWA ti san án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi, bí ọwọ́ mi ṣe mọ́ ni ó ṣe pín mi lérè. Nítorí tí mo ti pa ọ̀nà OLUWA mọ́, n kò ṣe ibi nípa yíyà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun mi.
Pín
Kà O. Daf 18O. Daf 18:19-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó mú mi jáde wá sínú ibi ńlá; Ó gbà mí nítorí tí ó ní inú dídùn sí mi. OLúWA ti hùwà sí mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi; gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi, ó ti fi èrè fún mi Nítorí mo ti pa ọ̀nà OLúWA mọ́; èmi kò ṣe búburú nípa yíyí padà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi
Pín
Kà O. Daf 18