ORIN DAFIDI 15
15
Ìwà tí Ọlọrun Fẹ́
1OLUWA, ta ni ó lè máa gbé inú àgọ́ rẹ?
Ta ni ó lè máa gbé orí òkè mímọ́ rẹ?
2Ẹni tí ń rìn déédéé, tí ń ṣe òdodo;
tí sì ń fi tọkàntọkàn sọ òtítọ́.
3Ẹni tí kò fi ahọ́n rẹ̀ sọ̀rọ̀ eniyan lẹ́yìn,
tí kò ṣe ibi sí ẹnìkejì rẹ̀,
tí kò sì sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn nípa aládùúgbò rẹ̀.
4Ẹni tí kò ka ẹni ẹ̀kọ̀ sí,
ṣugbọn a máa bu ọlá fún àwọn tí ó bẹ̀rù OLUWA;
bí ó bá jẹ́ ẹ̀jẹ́, kì í yẹ̀ ẹ́;
bí ẹ̀jẹ́ tí ó ti wù kí ó nira tó.
5Kì í yáni lówó kí ó gba èlé,
kìí sìí gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ aláìṣẹ̀.
Ẹni tí ó bá ṣe nǹkan wọnyi,
ẹsẹ̀ rẹ̀ kò ní yẹ̀ laelae.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ORIN DAFIDI 15: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010