ORIN DAFIDI 128

128
Ìbẹ̀rù OLUWA lérè
1Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bẹ̀rù OLÚWA,
tí ó sì ń tẹ̀lé ìlànà rẹ̀.
2O óo jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,
ayọ̀ ń bẹ fún ọ, yóo sì dára fún ọ.
3Aya rẹ yóo dàbí àjàrà eléso pupọ ninu ilé rẹ;
bí ọmọ tií yí igi olifi ká,
ni àwọn ọmọ rẹ yóo yí tabili oúnjẹ rẹ ká.
4Wò ó, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA yóo kẹ́ ẹni tí ó bẹ̀rù rẹ̀.
5Kí OLUWA bukun ọ láti Sioni!
Kí o máa rí ire Jerusalẹmu
ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.
6Kí o máa rí arọmọdọmọ rẹ.
Kí alaafia máa wà ní Israẹli.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 128: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀