ORIN DAFIDI 127

127
Abániṣé ni OLUWA
1Bí OLUWA kò bá kọ́ ilé,
asán ni wahala àwọn tí ń kọ́ ọ.
Bí OLUWA kò bá ṣọ́ ìlú,
asán ni àìsùn àwọn aṣọ́de.
2Asán ni kí á jí ní òwúrọ̀ kutukutu,
kí á tún pẹ́ títí kí á tó sùn.
Asán ni kí á máa fi làálàá wá oúnjẹ;
nítorí pé OLUWA a máa fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ ní oorun sùn.
3Wò ó! Ẹ̀bùn OLUWA ni ọmọ;
òun ní fi oyún inú ṣìkẹ́ eniyan.
4Bí ọfà ti rí lọ́wọ́ jagunjagun,
bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ìgbà òwúrọ̀ ẹni.
5Ayọ̀ ń bẹ fun ẹni tí apó rẹ̀ kún fún wọn.
Ojú kò ní tì í nígbà tí ó bá ń bá àwọn ọ̀tá rẹ̀ rojọ́ lẹ́nu bodè.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 127: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀