ORIN DAFIDI 126

126
Ẹkún Di Ayọ̀
1Nígbà tí OLUWA kó àwọn ìgbèkùn Sioni pada,#126:1 tabi Nígbà tí OLUWA mú àwọn eniyan Sioni pada.
ó dàbí àlá lójú wa.
2Ẹ̀rẹ̀kẹ́ wa kún fún ẹ̀rín, a sì kọrin ayọ̀,
nígbà náà ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ń wí pé,
“OLUWA mà ṣe nǹkan ńlá fún àwọn eniyan yìí!”
3Lóòótọ́, OLUWA ṣe nǹkan ńlá fún wa, nítorí náà à ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀.
4Dá ire wa pada, OLUWA,
bí ìṣàn omi ní ipadò aṣálẹ̀ Nẹgẹbu.
5Àwọn tí ń fọ́n irúgbìn pẹlu omi lójú,
jẹ́ kí wọn kórè rẹ̀ tayọ̀tayọ̀.
6Ẹni tí ń gbé irúgbìn lọ sí oko tẹkúntẹkún,
yóo ru ìtí ọkà pada sílé tayọ̀tayọ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 126: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀