ORIN DAFIDI 125

125
Ìfọ̀kànbalẹ̀ Àwọn Eniyan OLUWA
1Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA dàbí òkè Sioni,
tí ẹnikẹ́ni kò lè ṣí nídìí, ṣugbọn tí ó wà títí lae.
2Bí òkè ńlá ti yí Jerusalẹmu ká,
bẹ́ẹ̀ ni OLUWA yí àwọn eniyan rẹ̀ ká,
láti ìsinsìnyìí lọ ati títí lae.
3Eniyan burúkú kò ní ní àṣẹ
lórí ilẹ̀ àwọn olódodo,
kí àwọn olódodo má baà dáwọ́ lé ibi.
4OLUWA, ṣe oore fún àwọn eniyan rere,
ati fún àwọn olódodo.
5Ṣugbọn OLUWA yóo fi irú ìyà àwọn aṣebi jẹ
àwọn tí ó yà sí ọ̀nà àìtọ́.
Alaafia fún Israẹli!

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 125: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀