ORIN DAFIDI 129

129
Kí ojú ti ọ̀tá
1Ọpọlọpọ ìgbà ni wọ́n ti ń pọ́n mi lójú láti ìgbà èwe mi.
Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ wí pé,
2“Ọpọlọpọ ìgbà ni wọ́n ti ń pọ́n mi lójú láti ìgbà èwe mi,
sibẹ, wọn kò borí mi.”
3Wọ́n to ẹgba sí mi lẹ́yìn,
gbogbo ẹ̀yìn mi lé bíi poro oko.
4Ṣugbọn olódodo ni OLUWA,
ó ti gé okùn àwọn eniyan burúkú.
5Ojú yóo ti gbogbo àwọn tí ó kórìíra Sioni,
a óo lé wọn pada sẹ́yìn.
6Wọn óo dàbí koríko tí ó hù lórí òrùlé,
tí kì í dàgbà kí ó tó gbẹ.
7Kò lè kún ọwọ́ ẹni tí ń pa koríko;
kò sì lè kún ọwọ́ ẹni tí ń di koríko ní ìtí.
8Àwọn èrò ọ̀nà kò sì ní kí ẹni tí ń gé e pé:
“OLUWA óo fèrè síṣẹ́ o!
Ẹ kúuṣẹ́, OLUWA óo fèrè sí i.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 129: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀