ORIN DAFIDI 112
112
Ayọ̀ Ẹni Rere
1Ẹ yin OLUWA!
Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bẹ̀rù OLUWA,
tí inú rẹ̀ sì dùn lọpọlọpọ sí òfin rẹ̀.
2Àwọn arọmọdọmọ rẹ̀ yóo jẹ́ alágbára láyé,
a óo sì bukun ìran ẹni tí ó dúró ṣinṣin.
3Ọlá ati ọlà yóo wà ní ilé rẹ̀,
Òdodo rẹ̀ wà títí lae.
4Ìmọ́lẹ̀ yóo tàn fún olódodo ninu òkùnkùn,
olóore ọ̀fẹ́ ni OLUWA, aláàánú ni, a sì máa ṣòdodo.
5Yóo máa dára fún ẹni tí ó bá lójú àánú, tí ó sì ń yáni ní nǹkan,
tí ó ń ṣe ẹ̀tọ́ ní gbogbo ọ̀nà.
6A kò ní ṣí olódodo ní ipò pada lae,
títí ayé ni a óo sì máa ranti rẹ̀.
7Ìròyìn ibi kì í bà á lẹ́rù,
ọkàn rẹ̀ dúró ṣinṣin, ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA.
8Ọkàn rẹ̀ a máa balẹ̀, ẹ̀rù kì í bà á,
níkẹyìn, èrò rẹ̀ a sì máa ṣẹ lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀.
9Ó lawọ́, á máa ṣoore fún àwọn talaka,
òdodo rẹ̀ wà títí lae,
yóo di alágbára, a óo sì dá a lọ́lá.#2Kọr 9:9
10Ìbànújẹ́ yóo bá eniyan burúkú nígbà tí ó bá rí i.
Yóo pa eyín keke, yóo pòórá,
ìfẹ́ rẹ̀ yóo sì di asán.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ORIN DAFIDI 112: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010