1
ORIN DAFIDI 112:7
Yoruba Bible
Ìròyìn ibi kì í bà á lẹ́rù, ọkàn rẹ̀ dúró ṣinṣin, ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 112:7
2
ORIN DAFIDI 112:1-2
Ẹ yin OLUWA! Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bẹ̀rù OLUWA, tí inú rẹ̀ sì dùn lọpọlọpọ sí òfin rẹ̀. Àwọn arọmọdọmọ rẹ̀ yóo jẹ́ alágbára láyé, a óo sì bukun ìran ẹni tí ó dúró ṣinṣin.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 112:1-2
3
ORIN DAFIDI 112:8
Ọkàn rẹ̀ a máa balẹ̀, ẹ̀rù kì í bà á, níkẹyìn, èrò rẹ̀ a sì máa ṣẹ lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 112:8
4
ORIN DAFIDI 112:4
Ìmọ́lẹ̀ yóo tàn fún olódodo ninu òkùnkùn, olóore ọ̀fẹ́ ni OLUWA, aláàánú ni, a sì máa ṣòdodo.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 112:4
5
ORIN DAFIDI 112:5
Yóo máa dára fún ẹni tí ó bá lójú àánú, tí ó sì ń yáni ní nǹkan, tí ó ń ṣe ẹ̀tọ́ ní gbogbo ọ̀nà.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 112:5
6
ORIN DAFIDI 112:6
A kò ní ṣí olódodo ní ipò pada lae, títí ayé ni a óo sì máa ranti rẹ̀.
Ṣàwárí ORIN DAFIDI 112:6
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò