ORIN DAFIDI 113

113
Yíyin OLUWA fún Oore Rẹ̀
1Ẹ yin OLUWA!
Ẹ yìn ín, ẹ̀yin iranṣẹ OLUWA.
Ẹ yin orúkọ OLUWA.
2Kí á yin orúkọ OLUWA,
láti ìsinsìnyìí lọ títí laelae.
3Láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn,
kí á máa yin orúkọ OLUWA.
4OLUWA ju gbogbo orílẹ̀-èdè lọ,
ògo rẹ̀ sì ga ju ọ̀run lọ.
5Ta ló dàbí OLUWA Ọlọrun wa,
tí ó gúnwà sí òkè ọ̀run,
6ẹni tí ó bojú wo ilẹ̀
láti wo ọ̀run ati ayé?
7Ó gbé talaka dìde láti inú erùpẹ̀,
ó sì gbé aláìní sókè láti orí eérú,
8láti mú wọn jókòó láàrin àwọn ìjòyè,
àní, àwọn ìjòyè àwọn eniyan rẹ̀.
9Ó sọ àgàn di ọlọ́mọ,
ó sọ ọ́ di abiyamọ onínúdídùn.
Ẹ máa yin OLUWA.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 113: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀