Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, ẹ pe orúkọ rẹ̀, ẹ fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè. Ẹ kọrin sí i, ẹ kọ orin ìyìn sí i, ẹ sọ nípa gbogbo iṣẹ́ ribiribi rẹ̀. Ẹ máa fi orúkọ mímọ́ rẹ̀ yangàn, kí ọkàn àwọn tí ń wá OLUWA ó máa yọ̀. Ẹ wá ojurere OLUWA ati agbára rẹ̀, ẹ máa wá ojurere rẹ̀ nígbà gbogbo. Ẹ ranti iṣẹ́ ribiribi tí ó ti ṣe, ẹ ranti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ati ìdájọ́ rẹ̀.
Kà ORIN DAFIDI 105
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ORIN DAFIDI 105:1-5
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò