O. Daf 105:1-5
O. Daf 105:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa? ẹ pè orukọ rẹ̀: ẹ fi iṣẹ rẹ̀ hàn ninu awọn enia. Ẹ kọrin si i, ẹ kọ orin mimọ́ si i: ẹ ma sọ̀rọ iṣẹ iyanu rẹ̀ gbogbo. Ẹ ma ṣogo li orukọ rẹ̀ mimọ́; jẹ ki aiya awọn ti nwá Oluwa ki o yọ̀. Ẹ ma wá Oluwa ati ipá rẹ̀: ẹ ma wá oju rẹ̀ nigbagbogbo. Ẹ ma ranti iṣẹ iyanu rẹ̀ ti o ti ṣe; iṣẹ àmi rẹ̀ ati idajọ ẹnu rẹ̀
O. Daf 105:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, ẹ pe orúkọ rẹ̀, ẹ fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè. Ẹ kọrin sí i, ẹ kọ orin ìyìn sí i, ẹ sọ nípa gbogbo iṣẹ́ ribiribi rẹ̀. Ẹ máa fi orúkọ mímọ́ rẹ̀ yangàn, kí ọkàn àwọn tí ń wá OLUWA ó máa yọ̀. Ẹ wá ojurere OLUWA ati agbára rẹ̀, ẹ máa wá ojurere rẹ̀ nígbà gbogbo. Ẹ ranti iṣẹ́ ribiribi tí ó ti ṣe, ẹ ranti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ati ìdájọ́ rẹ̀.
O. Daf 105:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ fi ọpẹ́ fún OLúWA, ké pe orúkọ rẹ̀: Jẹ́ kí a mọ ohun tí ó ṣe láàrín àwọn orílẹ̀-èdè; Kọrin sí i, kọrin ìyìn sí i; sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ gbogbo. Ṣògo nínú orúkọ mímọ́ rẹ̀: Jẹ́ kí ọkàn àwọn tí ń wá OLúWA kí ó yọ̀. Wá OLúWA àti ipá rẹ̀; wa ojú rẹ̀ nígbà gbogbo. Rántí àwọn ìyanu tí ó ti ṣe, ìyanu rẹ̀, àti ìdájọ́ tí ó sọ