ÌWÉ ÒWE 8:33-36

ÌWÉ ÒWE 8:33-36 YCE

Ẹ gbọ́ ìtọ́ni, kí ẹ sì kọ́gbọ́n, ẹ má sì ṣe àìnáání rẹ̀. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá gbọ́ tèmi, tí ó ń ṣọ́nà lojoojumọ ní ẹnu ọ̀nà àgbàlá mi, tí ó dúró sí ẹnu ọ̀nà ilé mi. Ẹni tí ó rí mi, rí ìyè, ó sì rí ojurere lọ́dọ̀ OLUWA, ṣugbọn ẹni tí kò bá rí mi, ó pa ara rẹ̀ lára, gbogbo àwọn tí wọ́n kórìíra mi, ikú ni wọ́n fẹ́ràn.”