Owe 8:33-36
Owe 8:33-36 Bibeli Mimọ (YBCV)
Gbọ́ ẹkọ́, ki ẹnyin ki o si gbọ́n, má si ṣe jẹ ki o lọ. Ibukún ni fun ẹniti o gbọ́ temi, ti o nṣọ́ ẹnu-ọ̀na mi lojojumọ, ti o si nduro ti opó ẹnu-ilẹkun mi. Nitoripe ẹniti o ri mi, o ri ìye, yio si ri ojurere Oluwa. Ṣugbọn ẹniti o ṣẹ̀ mi, o ṣe ọkàn ara rẹ̀ nikà: gbogbo awọn ti o korira mi, nwọn fẹ ikú.
Owe 8:33-36 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ gbọ́ ìtọ́ni, kí ẹ sì kọ́gbọ́n, ẹ má sì ṣe àìnáání rẹ̀. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá gbọ́ tèmi, tí ó ń ṣọ́nà lojoojumọ ní ẹnu ọ̀nà àgbàlá mi, tí ó dúró sí ẹnu ọ̀nà ilé mi. Ẹni tí ó rí mi, rí ìyè, ó sì rí ojurere lọ́dọ̀ OLUWA, ṣugbọn ẹni tí kò bá rí mi, ó pa ara rẹ̀ lára, gbogbo àwọn tí wọ́n kórìíra mi, ikú ni wọ́n fẹ́ràn.”
Owe 8:33-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Fetí sí ìtọ́sọ́nà mi kí o sì gbọ́n; má ṣe pa á tì sápá kan. Ìbùkún ni fún ẹni tí ó fetísílẹ̀ sí mi, tí ń ṣọ́nà ní ẹnu-ọ̀nà mi lójoojúmọ́, tí ń dúró ní ẹnu-ọ̀nà mi. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi rí ìyè ó sì rí ojúrere gbà lọ́dọ̀ OLúWA. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti rí ń pa ara rẹ̀ lára gbogbo ẹni tí ó kórìíra mi fẹ́ ikú.”